EndSars: Igbimọ oluwadii sọ pe ki awọn oṣiṣẹ ajọ Sifu Difẹnsi meji fara han lori iku Idris Ajibọla

Alaga igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lati ṣewadii iwa awọn ọlọpaa SARS, Adajọ-fẹyinti Akin Ọladimeji, ti paṣẹ pe ki awọn oṣisẹ ajọ Sifu Difẹnsi meji fara han niwaju igbimọ naa lọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun yii.

Eleyii ko ṣẹyin bi Agbẹjọro Kanmi Ajibọla to n gbẹnusọ fun idile ọmọdekunrin kan, Idris Ajibọla, to padanu ẹmi rẹ lasiko ti awọn JTF n le mọto to wọ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja, ṣe rọ igbimọ naa lati fiwe pe awọn Sifu Difẹnsi ọhun.

A oo ranti pe ṣe ni Idris pẹlu awọn ọrẹ rẹ meji wa siluu Oṣogbo lati Ido-Ọṣun ti wọn n gbe lọsan-n ọjọ naa, bi wọn ṣe ra nnkan tan nile itaja nla kan l’Oṣogbo, ti wọn si n pada ni mọto awọn JTF, ninu eyi ti awọn ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ, sọja ati Sifu Difẹnsi wa, bẹrẹ si i le mọto wọn lọ.

Awọn ọmọdekunrin yii la gbọ pe wọn sare pẹlu ibẹru titi ti mọto wọn fi ko sinu koto nla kan lẹyin to fori sọ opo-ina onisimẹnti lagbegbe ọna East-Pass Dual Carriage, niluu Oṣogbo, loju-ẹsẹ si ni Idris ti ku, ti awọn JTF ọhun si sa lọ.

Idi niyi ti awọn obi Idris ṣe wa siwaju igbimọ oluwadii ọhun, wọn ni awọn fẹ kidaajọ ododo waye lori ọrọ iku ọmọ awọn, kijọba si san owo gba-ma-binu fun awọn.

Nigba tigbẹjọ naa tun pada bẹrẹ lọjọ Furaidee, Barisita Kanmi Ajibọla rọ igbimọ lati paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi meji ti wọn wa ninu mọtọ JTF naa fara han niwaju igbimọ lati waa sọ ohun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ ọhun.

O ni fifarahan wọn yoo tubọ tanmọlẹ kikun si iṣẹlẹ naa, yoo si ran iwadii ati igbẹjọ lọwọ kiakia niwọn igba ti awọn ti mọ oruko awọn mejeeji.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Akin Ọladimeji paṣẹ pe ki awọn Sifu Difẹnsi naa, ti wọn pe orukọ wọn ni Jimi Awoniyi ati Togun Babatunde, fara han niwaju igbimọ lọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun yii, o si sọ pe ki wọn fiwe ipe ranṣẹ si wọn kiakia.

 

Leave a Reply