Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Laaarọ kutu Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu keji yii, ni awọn Fulani kan ko wahala ba awọn ara Abule Bamajo, l’Ayetoro. Ṣugbọn ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ba mẹta ninu wọn.
Awọn Fulani yii dana sun awọn ile labule naa, wọn si tun ṣa Ismaila Alabi ladaa.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lo fi atẹjade ṣọwọ nipa iṣẹlẹ yii lọsan-an ọjọ Satide.
O ṣalaye pe wahala tawọn Fulani yii da silẹ de etiigbọ awọn ọlọpaa, wọn si mu awọn ọlọdẹ atawọn ọdọ kunra labule naa, wọn n wa inu igbo tawọn to ṣiṣẹ ibi naa sa si.
Nibi ti wọn ti n wọgbo kiri ni wọn ti de inu igbo kan ti wọn n pe ni Igboaje, nibẹ ni wọn ti ri Fulani kan torukọ ẹ n jẹ Musa Yusuf.
Ẹjẹ lo kun ara ada ti Fulani yii mu dani. Mimu ti wọn mu un naa lo ṣatọna bi ọwọ ṣe tun ba Usman Mohammed ati Aliyu Abubakar, awọn meji yii paapaa lọwọ si wahala to ba awọn ara abule Bamoja laaarọ kutu ọjọ naa. Wọn ṣe e tan ni wọn sa wọgbo.
Niṣe ni wọn sare gbe Ismaila Alabi to fara gbọgbẹ ada lọ sọsibitu fun itọju.
Ṣa, CP Edward Awolọwọ Ajogun ti ni ki wọn taari awọn tọwọ ba yii lọ si ẹka iwadii ọtẹlẹmuyẹ, ki wọn si wa awọn ọdaran Fulani yooku ri dandan.