Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọ dukia lo ṣofo ninu ijamba ina kan to waye lagbegbe ileewe girama Oyemẹkun, niluu Akurẹ, lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Ko sẹni to ti i le sọ ohun to ṣokunfa ijamba ina ọhun, ṣugbọn awọn eeyan lo ṣee ṣe ko jẹ ina ijọba ti wọn mu wa lojiji ni ina fi sẹ yọ lati inu yara kan, eyi to ran mọ odidi ile ọhun, to si jo o kanlẹ patapata.
Awọn ẹru olowo iyebiye bii aṣọ, tẹlifisan, ẹrọ amu-omi-tutu, aga ijokoo atawọn nnkan eelo ile mi-in ni ina naa sọ di eeru ki wọn too ri i pa.
Ohun ta a gbọ ni pe ko pẹ rara sigba ti ina ọhun bẹrẹ tawọn panapana ti wọn pe fi de sibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn wọn ko ri irinṣẹ ti wọn gbe wa lo titi wọn fi pada lọ.
Ina yii ti ba nnkan jẹ jinna ki awọn araadugbo atawọn oluworan too ri i pa pẹlu omi ati yeepẹ lẹyin-o-rẹyìn.
Ninu alaye ti araadugbo kan, Stella, ba akọroyin ALAROYE sọ, o ni oorun nnkan to n jona loun deedee gbọ lati ibi ti oun wa.
O ni igba toun gbiyanju lati yọju wo nnkan to n run loun ri eefin ina to n jade lati inu ọkan ninu awọn yara to wa ninu ile to jona.
Abilekọ Eyitayọ Oguntuaṣe to jẹ ọkan ninu awọn olugbe ile ọhun ni ẹyinkule loun wa ti oun n wẹ ọmọ nigba ti ina ọhun bẹrẹ.
O ni iwe-ẹri oun nikan loun raaye mu jade ki gbogbo ẹru oun yooku too jona mọle.
Adekunle Ajayi ni oun ko ri ohunkohun mu jade ninu awọn ẹru oun ati ti iyawo oun nitori pe ibi iṣẹ loun wa lasiko ti iṣẹlẹ ina ọhun waye.
Abilekọ Rachael Adejubẹẹ to jẹ lanleedi ile naa ti bẹbẹ fun iranlọwọ ijọba atawọn ẹlẹyinju aanu nitori pe ile to jona ọhun nikan loun fi n gbọ bukaata awọn ọmọ ti ọkọ oun fi silẹ saye lọ.