Wọn lu ọmọ ‘Yahoo’ pa ni Sagamu, wọn lo fẹẹ ji iya oniyaa to n gbalẹ ni titi gbe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

 

Ni fẹẹrẹ Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keji yii, ọmọkunrin kan ti wọn ni ‘Yahoo’ lo n ṣe jẹun, padanu ẹmi rẹ lagbegbe Ajegunlẹ, ni Ṣagamu.

Awọn eeyan to wa nitosi ni wọn fibinu lu u pa nitori wọn lo fẹẹ fi iya oniyaa to n gbalẹ oju titi jẹẹjẹ rẹ ṣowo.

Gẹgẹ bawọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣe ṣalaye, wọn ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ agbalẹ tijọba ni ki wọn maa gba titi ni iya naa. Iṣẹ ti wọn gbe fun un naa lo n ṣe lọwọ ti ọmọkunrin kan fi de ọdọ rẹ, to si fẹẹ fi nnkan gba a ko le gbe e sa lọ.

Bi iya ṣe ri eyi lo bẹ̀rẹ̀ si i sa lọ bi agbára rẹ ṣe mọ, bẹẹ lo n kigbe pe kawọn eeyan gba oun lọwọ ajinigbe naa.

Bi iya ṣe n sa lọ naa ni ẹni to n le e ko pada, awọn eeyan si sọ pe ọmọkunrin naa nìkan kọ lo wa. Wọn ni awọn ẹgbẹ rẹ kan wa nitosi pẹlu mọto ti wọn gbé wa, wọn yoo kan gbe obinrin naa ju sọkọ bi eyi to n le e ba fi raaye ba a, to si fi nnkan gba a ni.

 

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọkada to n ṣiṣẹ lọwọ idaji naa la gbọ pe wọn gba obinrin agbalẹ naa silẹ, wọn si le ọmọkùnrin to n le e naa mu, nítorí o ti fẹẹ sa wọbi kan lọ nigba to ri i pe iya naa ti sa asala.

 

Kíá lero ti pe le e lori, ti wọn bẹrẹ si i lu u, awọn kan tilẹ fẹẹ dana sun un ni, wọn ti gbe taya wa. Ṣugbọn iya to jẹ ọmọ ti wọn ni ‘Yahoo’ lo n ṣe naa pọ, ninu ẹ lo ti dagbere faye.

N ni kaluku ba fẹsẹ fẹ ẹ, kawọn agbofinro ma baa ka wọn mọbẹ.

Leave a Reply