Aṣẹ ile-ẹjọ ko di Eko lọwọ lati gba owo-ori ọja ( VAT) – Aṣofin Eko

Faith Adebọla

“Loootọ nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun paṣẹ pe kawọn tọrọ kan lori igbẹjọ to n lọ lọwọ nipa owo-ori ọja, VAT, ṣi dawọ duro sibi ti wọn de na, ṣugbọn aṣẹ naa ko ni ka ma gba owo-ori naa tori gẹgẹ ba a ṣe loye aṣẹ yii, ibi ti awa dawọ duro si ni pe a ti ṣe ofin, a si ti n lo o l’Ekoo, tori naa, a n gba owo-ori VAT niṣo ni tiwa ni o.”

Ọkan lara awọn aṣofin ipinlẹ Eko, to tun jẹ agbenusọ fun ileegbimọ aṣofin naa, Ẹnjinnia David Setọnji, lo sọ ọrọ yii di mimọ nigba to n dahun ibeere lori eto tẹlifiṣan ileeṣẹ Channels kan, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde yii.

Ọnarebu Sentọnji sọ pe ohun tawọn n ṣiṣẹ lori nipinlẹ Eko ni ofin tuntun ti Gomina Babajide Sanwo-Olu buwọ lu laipẹ yii lori VAT, ofin yẹn lawọn n tẹle, oun la si n muṣẹ. Ko ti i si igbẹjọ kan ni kootu nipa ofin yii, ko si si ipenija kan fun wa lori ẹ, tori naa, niwọn igba ti aṣẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yii ko ti darukọ ofin tuntun naa, ọrọ aṣẹ naa ko kan wa, dandan lowo-ori ni, ọran-anyan si laṣọ ibora.

Nigba ti wọn beere lọwọ aṣofin naa boya ipinlẹ Rivers ni wọn fẹẹ wo awokọṣe ẹ ti wọn fi sare gbe ofin tuntun yii kalẹ nipinlẹ Eko, Ọnarebu Setonji sọ pe “tipẹtipẹ nipinlẹ Eko ti n sọ pe eto iṣejọba Fẹdira ta a n lo lorileede yii ko wa deede, o labuku, o si nilo atunto atawọn atunṣe kan. Fun apẹẹrẹ, owo-ori ọja tawọn eeyan jẹ tabi nnkan eelo ti wọn lo ni owo-ori VAT ta a n sọ yii. Nibo lawọn eeyan ti wọn sanwo naa wa, Eko ni. Nibo ni ọja ti wọn jẹ tabi lo wa, Eko ni. Nibo lo ti yẹ karaalu janfaani owo-ori ti wọn n san naa, Eko ni. Ṣe ẹ ri i pe eto ti a ti n lo bọ tẹlẹ yẹn wọ gidi. Ni bayii, atunṣe ti de ba a. Loootọ lo jẹ pe ipinlẹ Rivers lo ṣaaju lọ sile-ẹjọ lori ọrọ yii, ṣugbọn ipinlẹ Eko ti n sọrọ nipa iku-diẹ-ka-a-to ilana naa tipẹ o.

Owo tipinlẹ Eko n pa lori owo-ori to ida marundinlọgọta lori ọgọrun-un (55%) apapọ gbogbo owo tawọn ipinlẹ yooku n pa loṣooṣu. Nigba ti Eko n pa ida marundilọgọta, ṣugbọn ti wọn yoo waa pin ida mẹwaa (10%) pere pada fun wa nigba ti wọn ba ki ọbẹ bọ owo naa, iyẹn o bojumu.”

Aṣofin naa tun sọ pe awọn oṣiṣẹ agbowoori ipinlẹ Eko, LIRS (Lagos Intenal Revenue Service) to tan, wọn si peregede lati gba owo-ori yii, wọn yoo ṣe bẹẹ. O lawọn ti fun wọn ni, ilana ati aṣẹ lati maa ba iṣẹ lọ ni tiwọn.

O ni owo naa maa wulo fun iṣẹ idagbasoke ilu, tori ọwọ to ba ṣẹ ẹgusi lo yẹ ko gbadun omitooro ọbẹ rẹ.

Leave a Reply