Aṣiṣe nla ni bi mo ṣe fi Agbọọla ṣe igbakeji mi – Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Asiṣe nla gbaa lo jẹ fun mi lori bi mo ṣe yan Agboọla Ajayi gẹgẹ bii igbakeji mi lọdun diẹ sẹyin. Eyi atawọn ọrọ aro mi-in lo n jade lẹnu Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, niluu Igbẹkẹbọ ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, lasiko to n polongo fun idibo abẹle ẹgbẹ naa ti yoo waye ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ to n bọ.

Akeredolu ni, aimọye ọrọ kobakungbe lawọn eeyan kan n sọ si oun lasiko ti oun fi erongba oun han lati mu Ajayi gẹgẹ bii alabaasisẹpọ lọdun naa lọhun-un.

Gomina ni oun ro nigba naa pe bi oun ṣe yan ọmọ bibi ilu Kiribo, ti i ṣe ilu iya oun lo n bi awọn eeyan ọhun ninu ti wọn fi ta ko igbesẹ naa, lai mọ pe aṣiyan patapata ni yoo pada jẹ fun oun.

Ọkunrin naa ni ohun to dun mọ oun ninu ju ni bi igbakeji oun ṣe waa pada fi iwa rẹ han fun gbogbo aye ri. Ṣe eefin ni iwa, ko si ba a ṣe le bo o mọlẹ to ti ko ni i ru jade to ba ya.

O rọ awọn eeyan ijọba ibilẹ naa ki wọn ma ṣe foya, nitori pe bi Ajayi ṣe kuro ninu ẹgbẹ APC lọ si PDP ko tu irun kankan lara awọn aṣeyọri ẹgbẹ,  o ni ṣe lo tubọ fẹsẹ awọn mulẹ si i.

 

 

Leave a Reply