Aṣiri nla! Idi ti Pasitọ Bakare fi d’ọrẹ Tinubu lojiji ree o

Ọjọ naa lo da bii ana yii. Ọjọ Sannde kan bayii, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2019 ni. O ti le lọdun kan bayii daadaa. Ọsan pọn ganringanrain, nitori aago mejila ọjọ naa ti kọja. Ṣugbọn niṣe ni inu gbọngan nla ti wọn wa tutu lolo, awọn ẹrọ amuletutu ibẹ n ṣiṣẹ karakara lai pariwo. Gbogbo ile nla naa dakẹ rọrọ, bi abẹrẹ ba bọ silẹ nibẹ, eeyan yoo gburoo rẹ gbọngidanrin! Ninu ṣọọṣi Latter Rain to wa ni Ọgba, l’Ekoo ni. Nibẹ ni Pasitọ nla nni, Pasitọ Tunde Bakare, ti n fọn bii erin, to n bu bii kinniun, ti ko si sẹni kan to le gbin, afi awọn ti wọn n pariwo ‘Haleluya’ nikan. Pasitọ naa gbohun soke, o si pariwo: “Ẹ wo o, latọjọ ti mo ti n ba yin sọrọ nibi yii, emi o sọ iru eleyii leti yin ri o! Bi ẹ ba ṣe iṣiro yin daadaa, ẹ oo ri i pe ninu awọn to n ṣejọba ni Naijiria, Aarẹ Muhammadu Buhari lo wa ni ipo kẹẹẹdogun, ṣugbọn nigba to ba gbejọba yii silẹ, emi ti mo wa niwaju yin yii ni yoo bọ si ipo kẹrindinlogun!”

Ni ariwo ba sọ ninu ṣọọṣi yii, nitori eti awọn olujọsin naa ti gbọ ohun ti wọn ko gbọ ri. Nitori bi gbogbo Naijiria ti to yii, ko si ojiṣẹ Ọlọrun kan to bọ si ori aga iwaasu, to si kede pe oun ni aarẹ Naijiria tuntun. Ati pe ta ni inu rẹ ko ni i dun, ṣe inu awọn ọmọ ijọ Latter Rain ko waa ni i dun dẹyin nigba ti wọn gbọ pe olori ijọ awọn ni yoo di aarẹ lẹyin Buhari. Yatọ si eyi, awọn naa kuku mọ pe Tunde Bakare to n sọrọ yii, ojiṣẹ Ọlọrun ti gbogbo aye bọwọ fun ni, ko si ni i sọrọ kan ti ko ba ṣe pe kinni naa da a loju. Ohun ti wọn mọ, tabi ti wọn ro, to si da wọn loju ni pe, bi Bakare ti n sọrọ nni, awọn ogun ọrun, tabi ko jẹ awọn ẹmi mimọ ni wọn duro ti i, awọn ni wọn si ko si i lẹnu to fi n sọ ohun to n sọ. Ohun to jẹ ki ariwo pọ ree bo ti sọrọ naa jade, nitori ọrọ naa ba ibi nla wọ inu eti wọn, wọn si mọ pe ohun ti yoo ṣẹlẹ ni Bakare n sọ.

Pasitọ Bakare ko ti i pari orin naa, o tun ni: “Ẹ wo o, ẹ gbe ọrọ mi yii lọ sori oke giga, nitori ẹ ko ti i gbọ iru ẹ ri. Mo fẹ ki ẹ mọ ni owurọ yii, pe ko si ohun to le yi i pada ni o. Lorukọ Jesu, oun Buhari lo wa ni ipo kẹẹẹdogun, emi ni mo wa ni ipo kẹrindinlogun. Ko si ohun to le yi i pada o. Ẹ wo mi daaada, ko si ohun to le yi i pada. Nitori ohun ti mo ṣe wa saye niyẹn, nitori ohun ti wọn si ṣe bi mi niyẹn, fun bii ọgbọn ọdun ni mo ti n gbaradi fun kinni yii, asiko naa ṣẹṣẹ to ni. Oun Buhari da bii Mose ni, o waa ko awọn ọmọ Israeli de eti odo Jordan, ṣugbọn ko le ko wọn kọja sodi keji odo. Oun ti ṣe iṣẹ ti wọn ran an pe ko waa ṣe o. Ṣugbọn Joshua kan yoo dide ti yoo ko awọn ọmọ Isreali bọ si oke odo lọhun-un, ti yoo si bẹrẹ si i pin awọn ohun ọrọ orile-ede fun awọn eeyan lati fi ṣe atunṣe aye wọn. Joshua naa ti de…!”

Bayii ni Bakare n sọrọ pẹlu idaniloju ti ẹnikan ko ri iru rẹ ri, awọn eeyan si ro pe ko si ohun meji to ṣẹlẹ, ko si idi ti ẹni kan yoo fi maa sọ eleyii bi ki i baa ṣe pe tọhun ti gbohun Ọlọrun. Lọrọ kan, gbogbo awọn ọmọ ijọ ****Latter Rain ro pe ọga awọn ti gbọ ohun Ọlọrun, ko si si ohun ti yoo da nnkan pada mọ, Tunde Bakare ni Joshua tuntun, oun ni yoo ko awọn ọmọ Naijiria de ilẹ ileri. Mose ni Buhari, ibinu ati agidi ko le jẹ ko ko ọmọ Naijiria debi kan. Ṣugbọn ọrọ oṣelu ko da bii ọrọ ki eeyan da ṣọọṣi rẹ silẹ ko si maa sọ ohun to ba wu u nibẹ. Ọrọ oṣelu, paapaa ti Naijiria yii, le ju bẹẹ lọ. Bi Bakare ti sọrọ lawọn oloṣelu ti dide, nitori awọn ko nigbagbọ pe ọrọ to n sọ yii, lati ọrun, tabi lori pẹpẹ Ọlọrun lo ti wa. Nigba to jẹ oloṣelu lawọn, ti wọn ko si ni iṣẹ meji, ti wọn ba n se’bẹ oṣelu nibi kan, koda ko jẹ maili mẹwaa lawọn wa, wọn yoo gbọ oorun ọbẹ naa daadaa. Wọn mọ pe ọbẹ ti Tunde Bakare n se yi, ọbẹ oṣelu pọnnbele ni.

Ohun to wa si wọn lọkan ni pe ọkunrin yii ti gba idaniloju kan lọdọ Aarẹ Buhari pe oun lawọn yoo gbejọba fun bi awọn ba n lọ, nigba to jẹ ọkunrin naa ni Buhari ti mu nigba kan lati ṣe igbakeji oun, ati pe Buhari ni igbẹkẹle ninu rẹ debii pe, bo ti n ṣejọba yii naa, oun ati Bakare ko yee ṣe wọle-wọde. Eyi lo fa a to jẹ gbogbo aburu yoowu ti ijọba yii n ṣe, boya awọn Fulani n paayan ni o, boya awọn Boko Haram gba ilu ni o, boya Buhari ko ri nnkan kan ṣe si wahala to wa nilẹ yii ni o, Pasitọ Bakare ko ni i wi nnkan kan. Bakare to ṣaaju awọn ọmọ Naijiria ni 2011 lasiko ti ijọba Goodluck Jonathan fi owo kun owo-epo nilẹ yii, gbogbo bi ijọba Buhari ṣe n fi owo kun owo-epo mọto yii kan naa lojoojumọ aye yii, ọkunrin oniwaasu nla naa ko ṣe bii ẹni pe oun ri wọn. Loju rẹ, ko si ohun to buru ninu rẹ bo ba ti jẹ Buhari lo fowo kun owo-epo.

Gbogbo eleyii lawọn oloṣelu Naijiria mọ, wọn si bẹrẹ si i wo Bakare pẹlu iran tuntun to ri yii, ati ọrọ to n sọ. Kia ni awọn ọmọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti dide, wọn bẹrẹ si i gbe oriṣiiriṣii igbimọ dide lati jẹ ki Bakare mọ pe bi wọn ti ṣe gbọn nile ọkọ, bẹẹ ni wọn gbọn nile ale, ati pe ere to rawọ le yii, ere egele ni o, awọn si mọ nipa rẹ daadaa. Bakare bẹrẹ si i rin mọ awọn aṣaaju Afẹnifẹre, o n tọ ojule awọn Yoruba to mọ, o si ba wọn ṣepade kan ni ilu Ikẹnnẹ, nibi ti Baba Ayọ Adebanjọ, Yinka Odumakin, Tokunbọ Awolọwọ-Dosumu ati Ọjọgbọn ‘Banji Akintoye pẹlu awọn mi-in wa. Eyi fihan pe Bakare ko gboju le ọrọ ẹmi ọrun nikan, o fẹ ki awọn ẹmi aye naa da si ọrọ yii, ki awọn aṣaaju Afẹnifẹre ati awọn aṣaaju Yoruba mi-in ba oun da si i. Ṣugbọn nibi ti Bakare ti n rin kiri yii, o ri kinni kan ti ko tẹ ẹ lọrun.

Ohun to ri naa ni pe ko si ibi ti o de ti ko kan ọwọ Bọla Tinubu. Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe bawo ni yoo ṣe ṣe ọrọ Tinubu si. Bẹẹ ki i ṣe akọkọ niyi ti oun ati Tinubu yoo pade ara wọn nidii ọrọ oṣelu, wọn ti jọ pade ara wọn lasiko ti wọn n dibo lọdun 2011, laye ijọba Jonathan. Nigba naa, Buhari jade, o fi Tunde Bakare ṣe igbakeji rẹ. Awọn mejeeji lọọ ri Bọla Tinubu pe ko jẹ ki awọn jọ ṣe aṣepọ, ki ẹgbẹ Buhari ati ẹgbẹ Action Congress, AC, tiwọn nigba naa jọ ṣe, ṣugbọn nnkan ko ṣiṣẹ laarin wọn nigba yẹn, ija ni wọn ja tuka. Ọkunrin oniwaasu yii mọ agbara Tinubu, o si mọ pe ti Tinubu ba jade loootọ, yoo ba oun fa kinni kan ti ko ni i tan nilẹ, ipo aarẹ to ti pariwo fun gbogbo aye si le ma ja si i lọwọ mọ. Ki la a ṣe ti ọrọ ba da bayii o? Ko si ohun meji ti eeyan yoo ṣe ju ko gbe ija ka ọta tabi alatako rẹ mọle lọ. Ohun ti Bakare si ṣe ree, o gbe ija tọ Tinubu lọ.

Lọjọ kan lo tun gori aga iwaasu rẹ, o si wi bayii pe: “Ara Bourdillon to n pa yin lẹ n sọ pe o lawọ, ti ẹ n sọ pe o n fun yin lowo, ohun ti gbogbo oju titi yin ṣe kun fun kidaa koto niyẹn, ti ẹ ko le wa mọto yin loju titi geere, nitori gbogbo owo to yẹ ki wọn fi tun ọna yin ṣe lawọn ara Bọdilọn ti ko jẹ lati igba ti ijọba tiwa-n-tiwa yii ti bẹrẹ. Awọn n gbe aye bii olowo-aye, wọn n ra ẹronpileeni ti wọn fi n ṣẹsẹ rin, wọn n kọle kiri bii ẹyẹ, wọn n kọle si Bọdilọn, wọn n kọle sibi, wọn n kọle sọhun-un, bẹẹ owo araalu ti wọn ji ko ni wọn fi n ṣe gbogbo ohun ti wọn n ṣe. Ṣugbọn ẹyin ọmọ Naijiria, awọn to n ba tiyin jẹ le maa n yin, ti ẹ maa n fi ijo pade wọn, awọn ti wọn ba fẹẹ tun tiyin ṣe lọta yin. Ẹni ti ẹ n pe pe o lawọ, o n fun yin ni nnkan yii, ọjọ n bọ ti yoo pọ gbogbo ohun to ko jẹ patapata.

“Ọjọ n bọ ti a ko ni i pe apọda yii ni ẹni to lawọ mọ, tabi ẹni to n ṣoore fawọn eeyan. Nitori ẹni to lawọ, tabi to jẹ oloore awọn eeyan loootọ, funra rẹ ni yoo fọwọ ara rẹ ṣiṣẹ ohun gbogbo to ba n fi tọrẹ. Nigba ti ọjọ naa ba de (lọjọ ti onibajẹ yii yoo pọ gbogbo ohun to ko mi), gbogbo oju to ba ri i ko ni i wo baibai, nigba ti ohun ti wọn ba ri yoo ye wọn; gbogbo eti to ba gbọ ọ paapaa yoo gbọ agbọye. Ọkan awọn oniwaduwadu paapaa yoo gbọn, yoo si sinmi jẹẹ lati gbọ agbọye imọ, awọn akololo paapaa yoo sọrọ yii, ọrọ ẹnu wọn yoo si da ṣaka. Lọjọ naa, ẹni ti ẹ n yin pe o lawọ yii, ọjọ naa ni yoo han si yin pe o n tan yin ni!” Bayii ni Tunde Bakare wi, ọrọ naa si wọ gbogbo eeyan leti loootọ, nitori pe wọn mọ pe Aṣiwaju Bọla Tinubu lo n gbe Bourdillon, l’Ekoo, ati pe oun lawọn eeyan sọ pe o lawọ, ẹran-bu-jẹ-bu-danu, nitori owo to maa n fun wọn.

Ọrọ naa ka awọn ọmọ Tinubu lara, o dun Tinubu funra rẹ, nitori wọn mọ pe gbogbo eleyii naa, Bakare fẹẹ sọ Tinubu di ẹni yẹyẹ ti ko yẹ ki wọn gbe de ipo aarẹ ni. Ṣugbọn Tinubu ati awọn eeyan rẹ ko yaa da si i, koda wọn ko dahun si ọrọ to ti ẹnu pasitọ naa jade. Amọ, awọn naa mura si ohun ti wọn n ṣe, wọn bẹrẹ si i ṣe kampeeni abẹlẹ kiri, bo si tilẹ jẹ pe Tinubu ko jade lati sọrọ, awọn ọmọ rẹ ti fọn ka igboro, bo si ti n nawo fun wọn nilẹ Hausa, lo n nawo fun wọn ni ilẹ Ibo, awọn eeyan si ti n jade loju mejeeji lati sọ pe oun lawọn fẹ ko waa du ipo aarẹ ni 2023. Ṣugbọn, ni tododo, Tunde Bakare ni Buhari fẹ, boya awọn ọmọọṣẹ Buhari fẹ ẹ tabi wọn ko fẹ ẹ ni ẹnikan ko le sọ. Idi ni pe bi a ti n wi yii, ọkunrin oniwaasu naa ti dero Abuja, Abuja lo n gbe ju lọ, Buhari si ti gbe awọn iṣẹ fun un to n ba a ṣe.

Eyi ni pe Buhari ti n fi oju rẹ mọ iṣẹ ijọba rẹ, wọn si ti n fi awọn ọna han an lori bi yoo ti ṣe to ba gbajọba. Nibi yii ni iṣoro mi-in ti koju Bakare, ọkunrin to ni oun yoo gbajọba lẹyin Buhari. Akọkọ ni pe bi Bakare yoo ba gbajọba lẹyin Buhari, ọkunrin naa yoo wa ninu ẹgbẹ oṣelu gidi, ko si si ẹgbẹ oṣelu gidi mi-in ti yoo wa ninu rẹ ju APC lọ, nitori ẹgbẹ ti Buhari n ṣe ree. Ninu APC si niyi, ki wọn too fa a kalẹ, yoo kopa ninu ibo abẹle ẹgbẹ naa, nibi ti wọn yoo ti na ọwọ rẹ soke bii ẹni ti yoo du ipo aarẹ. Bo ba waa jẹ bi nnkan ti wa ree, koda ki awọn ẹmi oriṣiiriṣii tẹle Bakare lati ọrun wa, ogun ti awọn ẹmi aye ti wọn wa ninu APC yoo gbe ko o, yoo le ju ohun ti apa rẹ yoo ka lọ. Bakare ko ni awọn eeyan kan bayii ninu APC, ko si si idi ti awọn ti ko mọ ọn ri bayii yoo fi maa sare tẹle e. Koda ki Buhari fẹran rẹ ju bẹẹ lọ, iṣoro ni fun un lati bori ninu ibo abẹle.

Awọn eeyan Buhari ti waa sọ fun un lẹyin pe gbogbo inawo ati irin ti Tinubu n rin kiri yii, o ṣee ṣe ko jẹ o kan n rin irin lasan ni, nitori awọn Buhari ko ni i fa a kalẹ lati du ipo aarẹ, koda bi APC fa a kalẹ, wọn ko ni i jẹ ko wọle, tabi ki wọn gbejọba fun un. ALAROYE gbọ pe ohun to fa a ree ti wọn fi ni ki Bakare mọ bi yoo ti rin mọ Tinubu, ti yoo si jẹ ki Tinubu duro sẹyin ẹ, nigba to ba ti han soun Tinubu pe awọn Buhari ko ni i jẹ ki oun ṣejọba. Awọn ti wọn n ba a to iṣẹ yii ni Abuja sọ pe bi Tinubu ba ti wa lẹyin rẹ, ti Tinubu ko si le du ipo aarẹ mọ, yoo ko gbogbo awọn ọmọlẹyin rẹ, ati ijokoo agbara oṣelu rẹ, fun un, ohun ti yoo si lo lati fi le bori ninu ibo abẹle yoowu ti wọn ba di ninu APC ree, ti ẹgbẹ naa yoo si fa a kalẹ, bo ba le jẹ loootọ ni wọn ti kọ ọ pe yoo di aarẹ Naijiria lẹyin Buhari. Nibi yii lo ti di dandan fun Tunde Bakare lati rin mọ Tinubu.

Igbesẹ akọkọ ni eyi ti Bakare gbe lọsẹ to kọja yii, nibi to ti jade lati sọ fun awọn agbaagba Yoruba pe ki wọn fi Tinubu lọrun silẹ, ki wọn yee bu u kaakiri. Bakare ni ko si ohun ti Tinubu ṣe ti ẹnikan ko ṣe ri, ati pe awọn agbaagba ti wọn n sọrọ rẹ lai daa yii, ilara lo n ṣe wọn, bi awọn naa ba ni anfaani iru eyi ti Tinubu ni, wọn yoo ṣe ju bẹẹ lọ. Bakare ni ki ẹnikẹni yee fi itan igbesi-aye Tinubu to ti re kọja lọ, ati awọn ohun to ṣẹlẹ si i ni kekere fi ba a ja, tabi ba a lorukọ jẹ mọ, nitori ko si ẹni ti ko ni irekọja tirẹ, kaluku lo ni awọn ohun to ṣe ti ko dara ni kekere. Pasitọ Bakare ni awọn agbalagba Yoruba ti wọn n binu Tinubu yii, wọn ko ni orukọ meji ju Agba Ṣakabula lọ. O ni agba Sakabula ni a o maa pe wọn nitori wọn ki i ṣe agbalagba daadaa. Bakare ni ohun ti Tinubu ti gbe aye rẹ ṣe, ko si ẹni to le ri i ṣe laarin awọn agbaagba ti wọn n binu rẹ kaakiri.

Bi Bakare ba ro pe ọrọ ti oun sọ yii yoo mu nnkan daadaa wa, aṣiṣe gbaa ni. Ọrọ naa bi ige, o bi adubi, awọn eeyan ko gba ohun ti ọkunrin ojiṣẹ Ọlọrun naa sọ rara. Akọkọ ni pe ori aga iwaasu lo ti duro to n ki oriki Tinubu to bayii, ori aga iwaasu naa lo wa to n bu awọn agbaagba Yoruba, nitori ọrọ oṣelu si ni. Yatọ si eyi, awọn eeyan ranti awọn ohun ti oun naa ti sọ nipa Tinubu sẹyin, wọn si ni ‘Pasitọ Ṣakabula’ loun funra ẹ, ko yee pe awọn kan ni agbalagba Ṣakabula. Ohun to wa buru ju ni pe ati Tinubu o, ati awọn ọmọ ẹyin rẹ o, ko si ẹni kan to gba ohun ti Bakare wi yii bii oore fun Tinubu, wọn ni bii igba ti eeyan fẹdi ọmọlakeji ẹ sita ni. Awọn ọmọ ẹyin Tinubu yii ni gbogbo aṣiri ti Bakare tu sita nipa Tinubu yii, ko sẹnikan to ran an, wọn ni o si ṣee ṣe ko jẹ ọkunrin naa lo ọrọ to sọ naa bii ọgbọn lati fi ṣakoba fun Tinubu ni.

Bẹẹ, ALAROYE gbọ pe ọrọ naa ki i ṣe bẹẹ. Ẹni to ba wa sọrọ ni ki i ṣe ohun ti Pasitọ Bakare fẹẹ ṣe ni lati fi Tinubu ṣe yẹyẹ, ohun to ṣe yii, o ṣe e lati fi fa oju Tinubu mọra ni, ki Tinubu le ti i lẹyin nigba ti ọrọ ba de oju rẹ, ko le ri i bii ẹni to yẹ ki oun duro lẹyin ẹ ko le di aarẹ. Ẹni naa ṣalaye pe awọn ọmọ Buhari ni wọn fun Bakare nimọran bẹẹ, nitori wọn sọ fun un pe gbogbo ọna ni ko fi fa oju Tinubu mọra, ko le ri ibo lati apa ilẹ Yoruba ko, ki wọn si le gba a sinu ẹgbẹ APC lai si inira.  Dajudaju, ibi ti ọrọ naa ja si fun Pasitọ Bakare yii, ko jọ pe o ro o tẹlẹ pe ibi ti kinni naa yoo ja si ree, ohun toun ti ro ni pe bi oun ba bu awọn agbaagba Yoruba yii daadaa, nigba ti wọn si jẹ alatako fun Tinubu, inu Tinubu ati awọn eeyan rẹ yoo dun soun, wọn yoo si maa ri oun bi olugbeja tootọ, awọn yoo si tibẹ di ọrẹ ara awọn.

Ṣugbọn ni bayii ọrọ ti bẹyin yọ, awọn ọmọ Tinubu ko fẹran ohun ti Bakare ṣe. Koda, aṣofin nla kan, Ṣọla Adeyẹye, jade pe oun koriira ohun ti Bakare ṣe fun Tinubu, pe alagabagebe gbaa ni! Bẹẹ Adeyẹye yii, ọkan ninu awọn aṣaaju APC to lagbara lẹyin Tinubu ni. Ọkunrin naa binu, o ni Bakare ko ṣe Tinubu loore, bẹẹ ni ko sọrọ to sọ yii lati fi kin Tinubu lẹyin ko le di aarẹ, o sọ ọ nisọ ibajẹ ni. Ko waa sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo pada ja si fun Pasitọ Tunde Bakare, tabi ọna ti ọkunrin oniwaasu ọrẹ Buhari naa yoo tun gba yọ. Ko ṣaa ni i le jade bayii ko sọ pe Ọlọrun ti tun sọ foun pe oun kọ loun yoo gbajọba lẹyin Buhari, bẹẹ ni yoo ṣoro lati sare da ẹgbẹ oṣelu tuntun silẹ lasiko ti ibo ku fẹẹrẹfẹ yii, ṣugbọn gẹgẹ bi oun naa ti wi o, ohun ti yoo ṣẹlẹ lori ọrọ yii laipẹ, gbogbo oju pata ni yoo ri i.

Leave a Reply