Aṣiri tu, eyi nidi ti ijọba orileede Benin fi ju Sunday Igboho sọgba ẹwọn

Jọkẹ Amọri

Latigba ti wahala to ṣẹlẹ lorileede Benin, lọgunjọ, oṣu keje yii, nibi ti wọn ti mu Sunday Igboho ni papakọ ofurufu wọn lasiko ti ajijagbara ọmọ Yoruba naa fẹẹ rin irin-ajo lọ si orileede Germany ni awuyewuye loriṣiiriṣii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.

Ireti gbogbo eeyan ni pe niwọn igba ti ile-ẹjọ to jokoo ni Cotonou, lorileede Benin ti fagi le awọn ẹsun ti ilẹ Naijiria n tori ẹ wa Igboho pe o n ko awọn ohun ija oloro kiri, o n dalu ru, bẹẹ lo lọ si Ibarapa, ti wọn si tun ni o fẹẹ fọ Naijiria si wẹwẹ. Awọn ọmọ Yoruba gbogbo, paapaa awọn alatilẹyin rẹ, ti ro pe ile-ẹjọ yoo tu u silẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja yii ti igbẹjọ naa tun waye.

Iyalẹnu si lo jẹ pe wọn ko tu ọkunrin naa silẹ, niṣe ni wọn tun ka awọn ẹsun mi-in si i lẹsẹ.

Yatọ si awọn ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ yii, kaka ki wọn gbe ọkunrin naa pada sọdọ awọn agbofinro to ti wa lẹyin ti igbẹjọ naa pari, ọgba ẹwọn ni wọn ni ki wọn maa gbe e lọ.

Latigba naa ni ALAROYE ti bẹrẹ iwadii to muna doko lati mọ idi ti wọn ṣe ju Sunday si ọgba ẹwọn, dipo ahamọ awọn ọlọpaa ti wọn sọ ọ si tẹlẹ.

ALAROYE ba awọn eeyan nla nla kan ti wọn wa nidii iṣejọba ilẹ Benin sọrọ, bo tilẹ jẹ pe a ko le darukọ wọn nitori ipo ti wọn wa, sibẹ wọn fi da wa loju pe otitọ pọnbele to wa nidii ọrọ naa lawọn ṣalaye fun wa, nitori awọn ri’le, awọn si r’ode nipa ohun gbogbo to n lọ lori ọrọ Sunday Igboho nitori ipo ti awọn di mu.

Alaye ti wọn ṣe ni pe nitori ijọba Naijiria ni wọn fi gbe Sunday kuro lọdọ awọn ọlọpaa, ti wọn gbe e lọ si ọgba ẹwọn ti wọn n pe ni Central, ni ilu Cotonou, lorileede Benin. Ọgba ẹwọn yii lo tobi ju nilẹ naa, inu igboro lo si wa, eeyan ko si le ku giri lọ sibẹ nitoriibi to wa jẹ ojutaye, aabo to si nipọn wa nibẹ.

Ọkunrin naa sọ pe, ‘‘Nitori ijọba Naijiria ni wọn fi gbe Sunday Igboho lọ si ọgba ẹwọn, nitori ẹru n ba ijọba Benin pe ijọba Naijiria le ran awọn eeyan ki wọn ṣe e leṣe mọbẹ, tabi ki wọn fi tipatipa ji ọkunrin naa gbe ni atimọle ọlọpaa to wa, ki wọn si maa gbe e lọ si orileede Naijiria nitori ara n ha wọn gan-an lati gbe e, gbogbo ọna ni wọn si n wa. Bi wọn ba si le gbe e, akoba ni yoo jẹ fun orileede Benin, nitori ọna ti ko bofin mu ni wọn fi fẹẹ gbe e. Ti ki i baa ṣe ilẹ Benin to n sa fun isọlẹnu, ti wọn si bọwọ fun ofin ilẹ wọn ati ti ọmọniyan, latọjọ yii nijọba Buhari iba ti da Igboho pada si Naijiria. Wọn o kan fẹ ko la ariwo lọ ni. Ijọba Naijiria ko si kọ boya ọna to bofin mu ni wọn gba tabi ọna ti ko bofin mu. Ṣẹ ẹ si mọ pe ilẹ Naijiria ni agbara lori ilẹ Benin ni awọn aaye kan, paapaa awọn ohun to ni i ṣe pẹlu eto ọrọ aje.

‘‘Niṣe ni wọn duro le ijọba ilẹ Benin lọrun lori ọrọ Igboho, gbogbo ohun ti wọn si fẹ ko ju ki wọn ri i pe awọn wa gbogbo ọna lati gbe e pada si Naijiria, lai ka awọn ofin to rọ mọ igbesẹ naa si. Ṣẹyin naa si mọ pe ijọba Naijiria ki i tẹle ofin bi ọrọ ba ti da bẹẹ.

‘‘Ijọba Naijiria mọ-ọn-mọ ma kọwe lati gba Sunday pada ni, nitori wọn ko fẹ ki oju wa lara awọn, nitori bi awọn eeyan ba mọ pe wọn kọwe, ariwo yẹn maa pọ, eyi lo fa a ti wọn ko fi kọwe, ti wọn ko si ran-an-yan wa sile-ẹjọ lọjọ ti igbẹjọ rẹ waye. Ki eyi le baa fi han pe wọn ko nifẹẹ si ẹjọ naa, ati ko le baa da bii pe ijọba Benin lo n ba a ṣẹjọ.’’

Ọkunrin yii ni irọ to jinna soootọ ni, gbogbo ẹnu loun si fi le sọ ọ pe ijọba Naijiria ko fi ilẹ Benin lọrun silẹ, gbogbo ohun ti wọn le ṣe ni wọn n ṣe, gbogbo ibi ti wọn si le rin si ni wọn n rin si lati ri i pe wọn gbe Igboho pada si ilẹ Naijiria, ṣugbọn nitori pe gbogbo awọn ọna ti wọn la silẹ ko ba ofin mu ni ilẹ Benin fi kọ lati ṣe ohun ti wọn fẹ.

ALAROYE yọ ọ gbọ pe nibi tọrọ naa ka ijọba Naijiria lara de, ko si ohun ti wọn ko ṣetan lati ṣe fun ilẹ Benin ki wọn le ri Sunday gbe kuro nibẹ.

Nibi ti ọrọ naa n lọ, wọn ko bikita lati ṣi ẹnubode orileede wọn ti wọn ti lati ọjọ yii wa nitori awọn eeyan ilẹ Benin.

Ijọba Naijiria ṣetan lati fi ọrọ Sunday Igboho ṣe paṣipaarọ fun ilẹ Benin, ki wọn ṣi ẹnu ibode ti wọn ti ti lati ọjọ yii wa. Bakan naa ni wọn le ko owo nla ti ko ni i ṣee kọ fun ijọba ilẹ Benin pe dandan, afi ki wọn ṣe gbogbo ọna ti ajijagbara ọmọ Yoruba yii yoo fi pada si Naijiria gẹgẹ bi ọkunrin yii ṣe sọ.

‘‘Ilẹ Benin naa nilo owo lati fi mu ọrọ aje ilẹ wọn dagba, bi ijọba Naijiria ba ko owo nla wa, o ṣee ṣe ki omi tẹyin wọgbin lẹnu o. Barubaru ni wọn yoo ṣe ẹjọ naa, kẹ ẹ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ajijagbara ọmọ Yoruba yii yoo ti pada si Naijiria.

‘‘Bo ba ṣe pe bi nnkan ṣe yẹ ko lọ ni, ka tiẹ ni wọn ba Igboho ṣẹjọ pe o wọlu lọna aitọ, ẹwọn oṣu mẹfa ni wọn yoo ju u si, lẹyin ẹwọn yii ni wọn yoo da a silẹ pe ko maa lọ. Aimọye awọn ọmọ Naijiria ti wọn gba mu, ti wọn si ṣẹwọn oṣu mẹfa yii, ti wọn si da wọn silẹ.

‘‘Ọna ti Igboho gba wọ Benin ati ẹri to wa pe ijọba Naijiria ti n wa a tẹlẹ, ti wọn si ti paayan nile rẹ jẹ anfaani to daa fun ajijagbara yii lati bọ lọwọ ijọba Benin nitori beeyan ba n sa fun iku, gbogbo ohun to ba le ṣe ni yoo ṣe lati ri i pe iku ko pa oun.

Ṣugbọn ijọba Naijiria ko fẹ iru eleyii rara. Wọn mọ pe bi Igboho ko ba si latimọle awọn, ariwo awọn ajijangbara ti wọn n fẹ orileede tiwọn yii ko ni i duro.’’

Bakan naa ni awọn to mọ nipa ofin sọ pe nitori pe ọrọ Igboho ni i ṣe pẹlu oṣelu, ko daju pe wọn le da a pada si ilẹ Naijiria gẹgẹ bi wọn ṣe n beere fun un. Ṣugbọn ijọba Naijiria buru, ko si ohun ti wọn ko le ṣe, ko si si iye ti wọn ko le na bo ba ti da bayii. Ati pe itiju nla ni yoo jẹ fun wọn bi Igboho ba pada lọ mọ wọn lọwọ. Eyi ni wọn ko fẹ ko ṣẹlẹ si awọn

‘‘Niṣe ni ki ẹ lọọ maa gbadura gidigidi, kawọn ọmọ Yoruba to ba si lagbara dide si ọrọ Sunday Igboho ki omi ma baa ti ẹyin wọ igbin lẹnu, nitori ijọba Naijiria ko duro rara.’’

Ọkunrin yii lo pari ọrọ rẹ bẹẹ.

Leave a Reply