Awọn ọlọpaa Amẹrika n wa Abba Kyari, wọn lo gbowo lọwọ ọmọ ‘Yahoo’

 Faith Adebọla

Bi gbogbo nnkan ṣẹ n lọ yii, ọrọ naa ti di bi wọn ba fa gburu, gburu yoo fa’gbo. Eyi ko sẹyin bi ijọba ọtẹlẹmuyẹ orileede ilẹ Amẹrika ṣe paṣẹ pe ki wọn mu igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa ilẹ wa, to tun jẹ olori ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ to maa n wadii iwa ọdaran to n ṣiṣẹ pẹ ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Abba Kyari, ki wọn si i gbe wa si orileede naa lati waa ṣalaye ohun to mọ nipa ẹsun owo kan ti wọn lo gba lọwọ Ramon Ọlọunwa Abass ti gbogbo eeyan mọ si Hushpuppi toun atawọn ẹgbẹ rẹ lu ilẹ Amẹrika atawọn orileede mi-in ni jibiti.

Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ile-ẹjọ kan nilẹ naa lo paṣẹ fun ẹka to n ṣe iwadii ẹsun ọdaran pe ki wọn ṣawari Kyari nibikibi to ba wa, ki wọn si maa gbe e bọ l’Amẹrika.

Wọn ni Hushpuppi atawọn ẹgbẹ rẹ marun-un mi-in, Abdulraham Juma, ẹni ọdun mejidinlọgbọn lati orileede Kenya, Chibuzor Vincent, ẹni ogoji ọdun to jẹ ọmọ Naijiria, Yusuf Anifowoṣe, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Rukayat  Faṣọla, ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Bọlatito Agbabiaka, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn  ni wọn lu ọkunrin oniṣowo kan ni ilẹ Dubai ni jibiti miliọnu ($1m) kan dọla. Irọ ti wọn pa fun un ni pe oṣiṣẹ banki lawọn, awọn si tun maa n ba awọn eeyan ṣe awọn eto loriṣiiriṣii lori iṣẹ ti wọn ba fẹẹ ṣe. Wọn ni awọn le ṣọna ti ọkunrin yii yoo fi ri owo nla ya ni banki Naijiria ti yoo fi kọ ileewe nla kan si Quatar.

O jọ pe ọkunrin yii ko si panpẹ awọn eeyan naa nitori ko mọ pe gbaju-ẹ ati onijibiti ni wọn. Lẹyin ti wọn ṣiṣẹ ibi wọn yii tan la gbọ pe ija bẹ silẹ laarin Hushpuppi ati Vincent, ọrọ naa si le debii pe Vincent n halẹ mọ Hushpuppi pe oun maa lọọ ṣofofo ohun tawọn ṣe fun oniṣowo nla ilẹ Dubai ti wọn lu ni jibiti naa.

Idunkooko mọ yii la gbọ pe o mu ki Ramon Abass ṣeto pẹlu Abba Kyari toun jẹ ọga ọlọpaa ti gbogbo eeyan mọ to ba ti di ọrọ ka ṣewadii iwa ọdaran, jibiti lilu, idigunjale to lagbara atawọn iwa ọdaran mi-in pe ko ba oun tanna wadii Vincent, ko si ri i daju pe wọn mu un. Kyari naa si ṣe bi ọkunrin yii ti beere, ko si pẹ rara ti wọn fi mu ọrẹ Ramon, Vincent, ti ọmọkunrin naa si dero ẹwọn.

A gbọ pe lẹyin ti Kyari ti mu Vincent, to si ti sọ ọ sẹwọn lo ya fọto ọmọkunrin naa lẹyin ti wọn mu un, to si fi ranṣẹ si Hushpuppi gẹgẹ bii ẹri pe iṣẹ naa ti di ṣiṣẹ. Bakan naa ni wọn ni o fi asunwọn banki kan ranṣẹ, nibi ti Hushpuppi yoo san owo iṣẹ to ba a ṣe, iyẹn bo ṣe ri i pe Vincent di mimu si.

Gbogbo awọn alaye yii lo jọ pe Hushpuppi ti tu si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orileede Amẹrika lọwọ ti ile-ẹjọ fi ni ki ilẹ Naijiria taari Kyari sawọn ko waa ṣalaye ohun to mọ nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii. Nitori ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji yii ti jẹwọ faọn ọlọpaa lọhun-un pe lootọ loun jẹbi, to si n bẹbẹ pe kawọn jọ dunaa dura lori ẹjọ naa ki wọn le wo o ṣe foun.

Eyi lo mu ki ọga ọlọpaa to jẹ igbakeji kọmiṣanna ti awọn eeyan fẹran daadaa, nitori bo ṣe maa n mu awọn ọdaran, awọn ole, apaayan atawọn onijibiti nibikibi ti wọn ba wọlẹ si yii ṣe awọn alaye kan sori ẹrọ ayelujara nipa ẹsun ti wọn fi kan an yii, ati bi ijọba Amẹrika ṣe ni wọn n wa a. O ni oun ko gbowo kankan lọwọ Ramon Abass.

Kyari kọ sori ẹrọ ayelujara pe ni bii ọdun meji ṣẹyin ni Hushpuppi pe ileeṣẹ awọn pe ẹnikan n dunkooko mọ ẹmi oun. O ni oju-ẹsẹ lawọn bẹrẹ iwadii, ninu iwadii lawọn si ti ri i pe ọrẹ lawọn mejeeji ati pe ọrọ owo lo da wọn pọ, ki i ṣe pe ẹnikan n lepa ẹmi rẹ gẹgẹ bo ṣe sọ. O ni lẹyin iwadii yii lawọn fi ọkunrin naa silẹ, awọn ko si beere tabi gba kọbọ lọwọ Ramon.

Ọga ọlọpaa naa ni ohun kan to tun pa oun ati ọkunrin ti wọn ti mu to wa niluu oyinbo yii pọ ni igba kan to ri awọn aṣọ ilẹ Hausa kan lori ikanni oun lori ẹrọ ayeluyara (facebook)  to si sọ pe awọn aṣọ naa rẹwa, oun si nifẹẹ lati ra iru rẹ. Kyari ni oun loun ṣe alarina rẹ pẹlu ẹni to n ta aṣọ yii, o si san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (300, 000.00) si asunwọn ẹni to fẹẹ ta aṣọ fun un naa.

O ni aṣọ yii ati fila oriṣii marun-un to ra ọhun ni wọn ko wa si ileeṣẹ awọn, to si ran ẹnikan ko waa gba a nibẹ.

Kyari ni lẹyin eleyii, ko sohun to jọ owo nla kan tawon kan n pariwo kiri pe oun gba lọwọ Hushpuppi abi ẹlomi-in. O ni ọwọ oun mọ, oun ko si lẹbọ lẹru rara.

 

Ṣugbọn ibeere tawọn eyan n beere ni pe o ṣe jẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn ko aṣọ Hushpuppi ti ẹnu ti n kun tipẹ lori ọna to n gba rowo ati bo ṣe n nawo bii ẹlẹdaa ko too waa di pe ọwọ pada tẹ e lorileede Dubai lọdun to kọja lo ko aṣọ wa.

Ẹsun jibiti, gbigbe owo lo soke okun lọna aitọ, wiwọ apo ikowosi awọn mi-in ji owo wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn tori ẹ mu ọkunrin yii atawọn ẹgbẹ ẹ kan lorileede Dubai ninu oṣu kẹfa, ọdun to kọja. Bi wọn si ṣe mu un ni wọn sọ ọ loko si ilẹ Amẹrika nitori aṣiri awọn jibiti owo nla to lu nibẹ naa ti wọn ti n tori rẹ wa a.

Latigba naa lo ti n jẹjọ awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii. Lasiko to si n rojọ lo n tu awọn aṣiri oriṣiiriṣii to waa pada kan Kyari yii.

Leave a Reply