Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, ti sọ pe dandan ni kawọn Fulani gbẹsan lara ẹnikẹni to ba rẹ wọn jẹ tabi ṣe wọn ni ṣuta, tori ẹya naa ko ṣee rẹ jẹ keeyan si ṣe e gbe.
O ni ṣugbọn to ba jẹ pe ile-ẹjọ lo fiya jẹ wọn nitori ẹṣẹ ti wọn ṣẹ, awọn Fulani maa n gba, wọn ki i gbẹsan.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, nibi apero ori atẹ ayelujara kan ti ẹgbẹ African Leadership gbe kalẹ ni gomina ọhun ti sọrọ yii gẹgẹ bii alejo pataki.
Ọrọ kan ti wọn lo sọ lọdun 2012 lori ikanni tuita (tweeter) ẹ pe “ẹnikẹni, boya o jẹ ṣọja tabi ki i ṣe bẹẹ, to ba pa Fulani, niṣe lo da bii igba ti tọhun lọọ yawo ni banki, dandan ni ko da owo naa pada lọjọ kan, bo ti wu ko pẹ to” ni wọn ni ki El-Rufai tanmọlẹ si ohun to ni lọkan.
O fesi pe: “Ti Fulani ba ku loju ogun, iyẹn yatọ. Ti wọn ba mu Fulani fun iwa ọdaran kan to hu, tawọn alaṣẹ si dajọ ẹ, ko sẹjọ ninu iyẹn. Ṣugbọn ohun ti Fulani o le gbagbe lae ni ti ẹnikan ba mọ-ọn-mọ fiya jẹ wọn lai nidii, tabi pa wọn, tijọba o si ṣe nnkan kan nipa ẹ. Fulani o ni i gbagbe o, ko si ni i dariji, o maa pada waa gbẹsan lara onitọhun ni, o pẹ o ya.
“Tori naa, ẹ gbọ mi ye o, ki i ṣe pe Fulani o le gbagbe ọrọ, ṣugbọn ti ọrọ naa ba lọwọ kan irẹjẹ ninu tabi ifiyajẹni lọna odi, ti ko si si idajọ ododo, ọrọ to yatọ pata ni, ẹsan maa waye dandan ni.