Jide Alabi
L’Ekoo, ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin ọmọ ọdun méjìdínlógún kan, Ṣẹgun Titilayọ, lori ẹsun pe o pa ololufẹ ẹ, o si sin in lai sọ fẹnikẹni.
Ọmọ ilu kan ti wọn n pe ni Otolu, nijọba ibilẹ Lẹkki, ni wọn pe ọkunrin yii, bẹẹ ni, ololufẹ ẹ ti wọn lọ pa yii n jẹ Oritokẹ Mannix.
Ileetura K.C Hotel, niluu Apakin, ni Lẹkki, l’Ekoo, ni wọn sọ pe Oritokẹ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn yii, ti n ṣiṣẹ ko too pade iku ojiji.
Lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn sọ pe wọn ti ri ọmọbinrin naa gbẹyin.
Awọn to sun mọ ọn sọ pe Ṣẹgun gan-an lo pe e lọjọ naa ni nnkan bii aago mọkanla aarọ.
Wọn ni latigba naa ni wọn ti ri alọ ẹ, ti wọn ko gburoo ibi to ra si, ki wọn too fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti.
Bọ ṣe ku dẹdẹ ki oṣu kan pe ti wọn ti n wa a ni aṣiri ohun to ṣẹlẹ si i tu.
Ileeṣẹ Adroan Homes, to n ṣiṣẹ lori ilẹ to ṣẹṣẹ ra si agbegbe Lẹkki, lo hu oku kan jade nibi ti katapila wọn ti n hulẹ kiri.
Wọn ni loju ẹsẹ lawọn alaṣẹ ileeṣẹ naa fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ninu iwadii wọn ni wọn si ti ri i pe oku Oritokẹ ti wọn n wa kiri ni.
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ wọn, ti wọn si ti mu Ṣẹgun sọdọ bayii, nibi to ti n sọ tẹnu ẹ lori bi Oritokẹ ṣe dẹni agbegbin bẹẹ yẹn.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Muyiwa Adéjọbí, ti sọ pe wọn ti gbe oku arabinrin naa lọ fun ayẹwo, ati pe Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ekoo, Hakeem Odumosu, paapaa ti kilọ fawọn obi lati mọ iru ẹni ti ọmọ wọn yoo maa tẹle kiri.
Bakan naa ni wọn lo ti sọ pe, ileeṣẹ ọlọpaa gbọdọ tu iṣu desalẹ ikoko lati mọ bọrọ ọmọ naa ṣe jẹ gan-an.