Aṣiri tu! Eyi lohun to fa ijamba baaluu to pa ọga agba Access bank, iyawo atọmọ rẹ

Faith Adebọla

Awọn alaṣẹ ijọba orileede Amẹrika ti ṣalaye ohun to ṣokunfa ijamba ọkọ ofurufu hẹlikọpita to ja lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, ọsu Keji yii, to si ṣeku pa eeyan mẹfa, ninu eyi ti ọga agba banki Access ilẹ wa, Access Holdings Limited, Ọgbẹni Hubert Onyewumba Wigwe, wa.

Wigwe, iyawo rẹ, Abilekọ Chizoba ati ọmọ wọn ọkunrin kan, to fi mọ ọga agba ileeṣẹ to n ṣe okoowo paṣipaarọ owo, Nigeria Exchange Group, NGX Group tẹlẹ, Ọgbẹni Abimbọla Ogunbanjọ, ati awọn pilọọti meji ti wọn dari helikọpita ọhun ni wọn ẹmi wọn sinu ijamba naa.

Ninu ipade pẹlu awọn oniroyin to waye laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, iyẹn ọjọ keji iṣẹlẹ buruku yii, Ọgbẹni Micheal Graham, to jẹ ọkan ninu awọn akọṣẹmọṣẹ kan ni ileeṣẹ to n ri si eto aabo awọn arinrin-ajo nilẹ Amẹrika, National Transportation Safety Board, sọ pe iwadii akọkọ ti wọn ṣe nipa ijamba naa ti fidi ẹ mulẹ pe oju-ọjọ ti ko ṣe kedere to wa lara okunfa iṣẹlẹ buruku yii.

O ni kurukuru maa n gba oju ọrun kan lasiko ọyẹ ati otutu to gbode nilẹ Amẹrika, eyi si ni ipilẹ akọkọ fun ijamba to fẹmi ṣofo ọhun.

Bakan naa lo lawọn eeyan tawọn ṣewadii lẹnu wọn, awọn tọrọ ṣoju rẹ, sọ pe oju-ọjọ naa ko ṣe kedere to laṣaalẹ ọjọ ti baaluu agbera-paa naa ja bọ, wọn ni winni-winni ojo ti n rọ, kurukuru si wa gidi.

O tun sọ pe helikọpita yii ki i ṣe iru eyi to maa n ni ẹrọ agbohunsilẹ tabi eyi to maa n ṣakọọlẹ awọn hulẹ-hulẹ irin rẹ, tori bẹẹ, oun o le sọ ju iwọnba awọn ẹri to wa larọọwọto lọ.

Amọ ṣa o, Micheal sọ pe iwadii to lọọrin ti n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, ti wọn yoo si fidi awọn nnkan mi-in to jẹ ki jamba naa waye mulẹ.

Bakan naa lo ni igbimọ to n ṣẹwadii awọn iṣẹlẹ pajawiri maa bẹrẹ ijokoo lori iṣẹlẹ ọhun, ti wọn yoo si fi orukọ ati awọn akọọlẹ mi-in nipa awọn to ba iṣẹlẹ buruku yii rin lede.

Baaluu agbera-paa Eurocopter EC-130 yii lo ja bọ lati oju ofurufu si adugbo Baker, ilu kan to wa ni Guusu/Iwọ-Oorun ilu Las Vegas, ni nnkan bii aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹẹẹdogun aṣaalẹ ọjọ Satide, ni hẹlikọpita ọhun gbera pẹlu awọn ero inu rẹ, ati awọn atukọ ofurufu meji, o gba Boulder City, ni Nevada, ko si ju iṣẹju mẹẹẹdogun pere lọ to fi ja, to si ṣeku pa gbogbo ero ati atukọ rẹ.

Oloogbe Hubert Wigwe yii tun ni oludasilẹ ati igi lẹyin ọga Wigwe University, to wa niluu Isiokpo, nipinlẹ Rivers.

Leave a Reply