Mọto ayọkẹlẹ fori sọ tirela ati kẹkẹ Marwa, eeyan meji ku, mẹta fara pa gidigidi

Mto aykl fori s tirela ati kkẹ Marwa, eeyan meji ku, mta fara pa gidigidi

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ, ọsibitu ijọba ‘General Hospital’, to wa lagbegbe Ọta, nipinlẹ Ogun, ni awọn ero mẹta kan ti wọn fara pa yannayanna  lasiko ijamba mọto kan to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lagbegbe Ọta-Idiroko, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun, wa bayii. Wọn ti n gba itọju lọwọ. Awọn meji ti wọn ku nibi iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti gbe pamọ si mọṣuari ileewesan naa titi tawọn eeyan wọn fi maa wa gbokuu wọn.

ALAROYE gbọ pe aṣaalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ni iṣẹlẹ ọhun waye laarin mọto ayọkẹle Toyota Camry kan ti ko ni nọmba idanimo lara ati tirela kan ti nọmba rẹ jẹ KRD 495 XQ pẹlu kẹkẹ Marwa kan ti nọmba rẹ jẹ AKD 380 QM. Ori biriiji Iju, ni asidẹnti ọhun ti waye, ti mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry ati tirela ọhun si ko sinu odo nla kan to wa labẹ biriiji naa. Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki awọn ọkunrin meji kan to wa ninu ọkọ ọhun fi jẹpe Ọlọrun loju-ẹsẹ, nigba tawọn mẹta mi-in ti wọn fara pa n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba agbegbe naa.

Alukoro ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo ‘Federal Road Safety Corps’ (FRSC), ẹka ti ipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpe, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun yii, sọ pe ere asapajude kan ti ọkan lara awọn dẹrẹba ọkọ ọhun n sa lọjọ naa lo ṣokunfa ijamba mọto ọhun, to fi mu ẹmi awọn kan lọ. Bakan naa lo ni ọpẹlẹpẹ pe awọn agbofinro bii: ọlọpaa agbegbe naa, oṣiṣẹ ajọ FRSC, ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi ati ẹṣọ ijọba ipinlẹ Ogun kan to n dari ọkọ laarin ilu, TRACE. Ifọwọ-sọwọ-pọ wọn lasiko ijamba ọhun lo ni awọn ṣe lanfaani lati tete yọ awọn mọto to ja sinu ọdọ ọhun sita, ti lilọ ati bibọ ọkọ si tete pada si bo ṣe wa tẹlẹ lagbegbe naa ni kia.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lọ bayii pe, ‘‘Eeyan marun-un ni wọn wa ninu ijamba mọto ọhun, agbalagba ọkunrin mẹrin ati agbalagba obinrin kan ṣoṣo. Agbalagba ọkunrin meji ati obinrin kan fara pa yannayanna nigba tawọn agbalagba ọkunrin meji ku loju-ẹsẹ. A ti gbe oku awọn to ku ninu iṣẹlẹ ọhun lọ sileewosan ijọba agbegbe naa, bakan naa ni awọn to fara pa nibi iṣẹlẹ ọhun n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba ta a gbokuu awọn to padanu ẹmi wọn lojiji ninu ijamba ọhun lọ.

Leave a Reply