Nitori asọtẹlẹ to sọ, ẹgbẹ APGA fẹẹ gbena woju Primate Ayọdele

Monisọla Saka

Ẹgbẹ oṣelu The All Progressives Grand Alliance (APGA), ti sọko ọrọ si gbajumọ wolii asọrọṣẹ nni, Primate Elijah Ayọdele, nitori iṣipaya to sọ nipa ijawe olubori Gomina to wa lori aleefa nipinlẹ Anambra, Charles Chukwuma Soludo, to ba di ọdun 2025.

Gẹgẹ bi ipalẹmọ eto idibo gomina mi-in ti yoo waye lọdun 2025 ṣe n lọ lọwọ nipinlẹ Anambra, Pasitọ Ayọdele ti jade sita gẹgẹ bii iṣe rẹ lati sọ iran to ri nipa ẹni ti yoo wọle ibo.

O ni ti ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, iyẹn All Progressives Congress (APC), ba le fa eeyan nla kan to gbajumọ silẹ nipinlẹ Anambra, onitọhun ni yoo le Soludo wọle, ti yoo si dena rẹ lati ṣe saa keji gẹgẹ bii gomina ipinlẹ ọhun.

Nigba ti wọn n fesi si ohun ti Ayọdele sọ, awọn ikọ oniroyin ẹgbẹ oṣelu APGA, (APGA Media Warriors Forum), naka aleebu si Ayọdele, bẹẹ ni wọn ni o kundun ko maa fi orukọ Ọlọrun parọ nibi iṣipaya eke rẹ.

Ninu atẹjade ti adari gbogbogboo fun ẹgbẹ APGA, Chinedu Obigwe, fi sita lo ti ni pẹlu ọpọlọpọ iṣẹ ribiribi ni Soludo ti ṣe silẹ, o ti dami siwaju lọdọ awọn araalu, o si daju pe oun ni yoo wọle gomina ọdun 2025.

O ni, “Ma a rọ Primate Ayọdele lati yee lo orukọ Ọlọrun lori asan. Wolii ọjọ ikẹyin kan ni mo ri i si, ọpọlọpọ awọn iṣipaya rẹ ni ki i si i wa si imuṣẹ.

” Awa ti a jẹ alatilẹyin tọkan tọkan fun Gomina Soludo n gbadura fun ọmọ ẹgbẹ APC to ni ko gbegba ibo yẹn, ka le kọ ọ lọgbọn oṣelu ti ko ni i gbagbe laye ẹ.

“Mo n sọ ọ lai fikan bọkan pe ọna lati mu ki ẹgbẹ APGA ko gbogbo ibo wọọdu ọọdunrun ati mẹrindinlọgbọn (326), to wa nipinlẹ Anambra ni ti ẹgbẹ APC ba ba wa figa gbaga”.

O loun n ke si Ayọdele bayii lati jade sita waa sọ gomina to tíì ṣiṣẹ to lapẹẹrẹ to Soludo, ti ko ti i lo to ọdun meji nipo.

O ni oju Ayọdele ni yoo ṣe nigba ti Soludo ba gbegba oroke lọdun to n bọ.

 

Leave a Reply