‘A FẸẸ MỌ IKU TO PA ỌMỌ WA O,’ AWỌN YORUBA KOGI BINU

Ọrọ iku to pa ọmọọbinrin afẹronpileeni-jagun, Tolulọpẹ Arotile, ko ti i tan nilẹ rara, nitori iruju ti ọrọ iku rẹ mu dani. Gbogbo eeyan lo saa n sọ pe ọrọ iku naa ko ye awọn. Ṣe loootọ lọrẹ ẹ fi rifaasi mọto pa a ni? Ṣe kinni ọhun ṣeesi ni? Abi wọn mọ-ọn-mọ pa a ni? Gbogbo ibeere yii wa ninu ohun tawọn Yoruba ipinlẹ Kogi n tori ẹ binu bayii o.

Ẹgbẹ awọn ọmọ abinibi Okun (Okun Developmet Association) ni gbogbo alaye ti awọn eeyan ijọba n ṣe lori iku Tolulọpe yii kan n mu inu bi awọn ni, nitori ọrọ naa ko ba ara wọn mu. Wọn ni ọtọ ni wọn sọ pe ọmọọleewe ẹlẹgbẹ rẹ kan to ti ri i tipẹ ni inu ẹ dun to sare da mọto rẹ duro, to gbe e si rifaasi, ki mọto naa too kọlu Tolulọpẹ to si pa a. Ọtọ ni iroyin sọ pe awọn ti wọn n wa mọto naa ki i ṣe ọmọleewe ẹ rara, alejo ni wọn ninu ọgba naa. Ọtọ ni wọn sọ pe ẹni ti wọn lo wa mọto yii ko ni lansẹnṣi, ati alaye oriṣiriṣii to ṣoro lati di mu gbogbo.

Ẹgbẹ awọn ọmọ Okun yii wa ni ko si ohun ti ijọba apapọ le ṣe ti yoo tẹ awọn lọrun ju ki iwadii to rinlẹ gidi jade lori ọrọ iku yii lọ. Wọn ni ohun ti awon ṣe n sọ bẹẹ ni pe bo tilẹ jẹ ọmọ kekere ni Tolulọpẹ, ipa to fi ẹronpileeni ijagun rẹ ko ninu ogun awọn Boko Haram ati awọn afẹmiṣofo mi-in to n lọ nilẹ Hausa yii ko kere, o si ṣee ṣe ko jẹ pe oju ti wa lara rẹ pe ọga nla kan ni yoo da lọla, ki awọn kan si fẹe di i lọwọ. Ṣugbọn ootọ to wa nidii eyi ko ni i jade sita afi ti ijọba ba ṣe iwadii gidi.

Lati ọjọ ti Tolulọpẹ ti ku lawọn eeyan ti n kaaanu, ti wọn si n kẹdun, nitori pe akanda ọmọ  kan ni i ṣe, bi wọn ko ba si da ẹmi rẹ legbodo ni, eeyan nla kan ni iba jẹ lorilẹ-ede yii lẹyin ọla.

 

Leave a Reply