A ko fi kun owo ileewe kankan ni Kwara – kawu

 Stephen Ajagbe, Ilọrin

Bi awọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ Kwara ṣe n pada sẹnu ẹkọ wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ijọba ti ta ko ahesọ kan to n tan kiri lori afikun owo ileewe, wọn si ti ṣekilọ fawọn alaṣẹ ileewe ijọba lati ma fi kun owo tawọn akẹkọọ n san.

Kọmiṣanna feto ẹkọ lawọn ileewe giga ni Kwara, Hajia Sa’adatu Modibbo Kawu, lo sọrọ ọhun nibi ipade ati idanilẹkọọ nipa ilana lati dena atankalẹ arun Covid-19 to ṣe pẹlu awọn tọrọ kan lẹka eto ẹkọ, eyi to waye lọsẹ to kọja niluu Ilọrin.

Atẹjade kan latọwọ Akọwe iroyin rẹ, Adamu Mohammed Saidu, ṣalaye pe ijọba ko ni i gba ileewe giga kankan laaye lati maa gba owo to ba ju agbara awọn obi lọ lọwọ awọn akẹkọọ.

Kọmiṣanna ọhun to ta ko ahesọ to n kaakiri pe ijọba ti fi kun owo igbaniwọle (Acceptance fee) ni KWASU to wa niluu Malete, o sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ rara.

O rọ araalu, paapaa awọn akẹkọọ ati obi, lati ma gba ọrọ naa gbọ, o ni ahesọ lasan ni.

O gba awọn akẹkọọ atawọn olukọ nimọran lati maa tẹle gbogbo ilana tijọba atawọn oṣiṣẹ eto ilera ti la kalẹ lati gbogun ti arun korona kaakiri inu ọgba ileewe wọn.

Leave a Reply