A ko ni i gba ẹnikẹni laaye lati dibo lai lo ibomu – Ajọ eleto idibo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ajọ eleto idibo orilẹ-ede yii ti ni ko ni i saaye fun ẹnikẹni ti ko ba lo ibomu lati dibo ninu eto idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ondo lọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ yii.

Festus Okoye to gbẹnusọ fun ajọ naa nibi idanilẹkọọ kan ti wọn ṣe fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni igbesẹ yii jẹ ọkan lara awọn ilana ti ajọ to n mojuto didena itankalẹ arun Korona nipinlẹ Ondo fi lelẹ fun gbogbo awọn to ba fẹẹ kopa ninu eto idibo naa.

Kọmisanna ẹka to n ri ṣeto idanilẹkọọ ọhun ni awọn ko ni i gba fun ẹnikẹni lati lo ibomu ti wọn kọ orukọ ẹgbẹ tabi ṣami si lara lawọn ibudo idibo to wa kaakiri ipinlẹ Ondo lọjọ naa.

Bakan naa lo ni awọn osisẹ to to bii ẹgbẹrun mẹtadinlogun lawọn fẹẹ lo fun eto idibo ipinlẹ Ondo nikan.

Leave a Reply