A maa gbẹsan iku Fulani ati maalu wọn ti wọn pa nilẹ Yoruba – Miyetti Allah

Awọn Fulani darandaran ti ẹgbẹ wọn n jẹ Miyetti Allah Kautal Hore, ti sọ pe ko ṣeni to le ni ki awọn kuro nilẹ Yoruba nitori o wa ninu ofin Naijiria daadaa pe ko sibi ti awọn ko le gbe lorilẹ-ede yii.

Ninu ọrọ ti Ọgbeni Alhassan Saleh, ẹni ti i ṣe akọwe gbogbo-gboo fun ẹgbẹ awọn Fulani darandaran yii ba iwe iroyin ‘The Punch’ sọ lo ti sọ pe ẹnikẹni to ba huwa ọdaran ninu awọn ni ki ijọba fọwọ ofin mu, ki wọn si fi iya to tọ jẹ iru ẹni bẹẹ.

 

Ọkunrin yii fi kun un pe gbogbo awọn ti wọn n pariwo pe ki awọn ko ẹru awọn kuro nilẹ Yoruba, iru igbesẹ bẹe yoo ṣoro gidigidi.

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe gbogbo ẹran ti awọn eeyan pa, ati awọn eeyan awọn ti wọn da ẹmi wọn legbodo pata lawọn yoo gba ẹsan ẹ, nitori awọn ko le fara mọ iyanjẹ.

Saleh fi kun ọrọ ẹ pe iwa ika ati ọdaju ni bi wọn ṣe ni ki awọn Fulani darandaran kuro nilẹ Yoruba, ati pe ki i ṣe gbogbo Fulani naa ni ko dara, eyi to ba ti ṣẹ, ọwọ ofin ni ki wọn fi mu iru ẹni bẹẹ.

O ni niṣe lo yẹ ki ijọba pese ibi ti awọn ẹran ti awọn n sin yoo ti maa jẹko, dipo bi wọn ṣe ni ki awọn kuro nilẹ Yoruba patapata.

Ọkunrin Fulani yii sọ pe awọn ko nibi i lọ rara, nitori ọmọ Naijiria lawọn naa, bẹẹ lẹnikan ko le sọ pe ibi kan bayii ni ki awọn rin si, tabi ibi kan ni awọn ko gbọdọ lọ ni gbogbo ibikibi ni Naijiria.

Bẹẹ lo tẹnumọ ọn pe, “Ko si ẹnikan bayii to lẹtọọ lati le wa kuro ni ipinlẹ kankan, ti ẹ ba si sọ pe ẹ fẹẹ le wa, awa naa ko ni i gba a fun yin. Bẹẹ lẹnikẹni ko lẹtọọ lati pa Fulani kankan, ẹni to ba ṣe e, ki oun naa ma lọọ sun fọnfọn o, awa naa yoo gbẹsan iku eeyan wa ti ẹnikẹni ba pa. A ko koriira ẹya tabi iran kankan, ẹmi kan naa ni gbogbo wa gbe sọrun, eeyan ko si ni i pa Fulani ki awa naa maa woran.”

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe bi ọrọ ṣe ri gan an ni Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed, ṣe sọ ọ yẹn, pe ko si ẹnikan to gbọdọ sọ pe ki awọn ẹya kan kuro nipinlẹ kan, nitori ọmọ Naijiria ni gbogbo wa.

Ṣiwaju si i, o tun sọ pe, “Ohun to ṣe ni laaanu ni pe awọn Fulani ti awọn eeyan n kọ lu bayii ki i ṣe awọn janduku ti wọn ṣẹ, awọn ti ko mọwọ mẹsẹ ni wọn n fiya jẹ, bẹẹ nijọba to yẹ ko gbe igbesẹ n woran, ohun to si n ṣẹlẹ yii le di wahala nla ti apa ko ni i ka.”

Bẹẹ gẹgẹ ni olori awọn Miyetti Allah lawọn ipinlẹ Guusi-Ila-Oorun atawọn ti Guusu-Guusu lagbegbe awọn ipinlẹ bii Delta, Edo, Rivers lọhun-un ti sọ pe awọn ko ṣetan lati fi agbegbe ọhun silẹ pada si ilẹ Hausa.

Leave a Reply