Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori bawọn akẹkọọ kan lawọn ileewe nipinlẹ Ogun ṣe bẹrẹ si i lu tiṣa, ti awọn obi mi-in naa n ko janduku lọ sileewe lati gbeja ọmọ wọn ti tiṣa ba ba wi, ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọmọkọmọ tọwọ ba tẹ pe o lu tiṣa, o daamu ileewe lọna kan tabi omi-in to le da wahala silẹ, awọn yoo le ọmọ bẹẹ kuro nileewe, ijọba yoo si tun ba a ṣe ẹjọ.
Kọmiṣanna fun eto ẹkọ, Sayẹnsi ati Imọ-ẹrọ nipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, iyẹn lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abẹokuta.
Ọjọgbọn Arigbabu sọ pe gbogbo akẹkọọ to ba gbimọ-pọ pẹlu awọn yooku rẹ lati da omi alaafia ileewe ru nijọba yoo maa mu bayii, ti wọn yoo le wọn danu, ti wọn yoo si tun foju bale-ẹjọ.
O fi kun un pe awọn tọwọ ti ba lori ẹsun yii ti wa ni kootu lọwọlọwọ.
Kọmiṣanna yii sọ pe ileeṣẹ oun yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro bii ọlọpaa lati asiko yii lọ. O ni awọn sifu difẹnsi naa yoo ba awọn ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹṣọ fijilante so-safe, ki alaafia to ti fẹẹ kuro lawọn ileewe yii le pada sibẹ.
“Idaamu ọkan ni bawọn janduku ṣe n waa lu awọn tiṣa ninu ileewe lasiko yii n jẹ fun Gomina Dapọ Abiọdun, o si koro oju si iṣẹlẹ naa gidi. Akẹkọọ yoowu tọwọ ba tẹ pẹlu awọn yooku ẹ pe wọn n lọwọ si iwa buruku yii yoo jiya gidi labẹ ofin. Ilu awọn ọmọluabi ti wọn jẹ ẹni apọnle ni gbogbo eeyan mọ ipinlẹ Ogun si, a o ni i gba iwakiwa ti yoo ba wa lorukọ jẹ laaye rara.” Bẹẹ ni Ọjọgbọn Abayọmi Arigbabu wi.
O ni ileeṣẹ oun yoo wadii ohun to n fa iwakiwa to fẹẹ gbilẹ yii, awọn yoo si wa ojutuu si i.
O rọ awọn tiṣa naa pe ki wọn maa ṣe deede pẹlu iwa rere nibi gbogbo. Bakan naa lo rọ awọn obi ti wọn ba ni ifisun pe ki wọn lọ sọdọ ọga ileewe tabi ileeṣẹ eto ẹkọ, o ni ẹsẹkẹkẹsẹ lawọn yoo bojuto o.