A maa yọ owo iranwọ ori epo danu, aabo si maa duro digbi lasiko yii-Tinubu

Faith Adebọla

Aarẹ tuntun ilẹ wa, Bọla Ahmed Tinubu, ti sọrọ lori awọn nnkan to maa fi ṣe afojusun bi wọn ṣe n bura fun un gẹgẹ bii Aarẹ kẹrindinlogun nilẹ wa.

Tinubu sọrọ ọhun ninu ọrọ akọsọ rẹ tọpọ eeyan tẹti bẹlẹjẹ si ni gẹrẹ ti wọn ṣebura wọle fun un tan gẹgẹ bii Aarẹ lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.

Ni pato, Tinubu mẹnu ba ọpọ ẹka ti eto iṣakoso rẹ yoo fọwọ ba bii eto aabo, ọrọ-aje, ipese iṣẹ, iṣẹ agbẹ, ipese nnkan amayedẹrun gbogbo, ẹkunwo ori epo rọbi, paṣipaarọ owo Naira wa pẹlu tilẹ okeere, ajọṣe orileede sorileede, atawọn nnkan mi-in.

Lori awuyewuye afikun owo -ori epo rọbi tawọn eleebo n pe ni subsidy, Tinubu ni oun gboṣuba fun bi ijọba Buhari to kuro lori aleefa ti ṣe gbiyanju gidigidi lati jawọ ninu afikun owo naa, tori niṣe leto naa n ṣe awọn ọlọrọ loore, to si n ni mẹkunnu lara. O ni ni toun, ko si awijare kankan feto sọbusidi to n fojoojumọ roke lala si i, ti ko si sowo lati fi kaju gbese rẹ. Tori bẹẹ, niṣe lawọn maa kuku dari owo sori awọn nnkan amayedẹrun bii eto ilera, ẹkọ iwe, ipese iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, eyi to maa ṣe ọpọ miliọnu araalu loore ju fifi owo rọgun-rọgun sanwo ori epo lọ. Lede kan, Tinubu loun loun ko ni i san afikun owo-ori epo.

Lori eto aabo to mẹhẹ, Aarẹ ni ori ookan aya ijọba oun lọrọ aabo maa wa, tori ko le si aasiki tabi idajọ ododo kan nibi ti iwa ipa ati aisi aabo ba wa. Ki eto aabo le lagbara, o loun maa ṣatunyẹwo awọn ilana ati eto ipese aabo, awọn si maa nawo gidi sori eto aabo. O lawọn maa ṣedalẹkọọ, awọn maa pese irinṣẹ igbalode, ati nnkan ija lagbara gidi ti yoo le kapa awọn ọta.

Leave a Reply