Asawo tilu Ayetẹ, Ọba Emmanuel Okeniyi, ti sọ pe awọn o ni i gba ki afurasi ọdaran Fulani, Iskilu Wakili, ti wọn mu laipẹ yii, atawọn ẹmẹwa ẹ to ṣẹku tun pada sagbegbe naa mọ, bẹẹ lọba alaye naa ni iyalẹnu ni bi ijọba ṣe sọ awọn ọmọ OPC to mu Wakili satimọle, o ni igbesẹ naa ku diẹ kaato.
Ninu ọrọ to ba ALAROYE sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lori foonu nipa awọn iṣẹlẹ to waye lagbegbe naa, ati wahala tawọn ọmọ-ẹyin Wakili n da silẹ lẹyin ti wọn ti mu ọga wọn, lo ti sọ pe akoba gidi ni igboke-gbodo awọn Fulani nilẹ Ibarapa, o ni wọn ti mu ki owo ounjẹ gbowo lori bayii.
Aṣawo ni, “Ki i ṣe ọrọ ọdun marun-un ti Wakili ti n ṣẹ Yoruba, to n huwa ibi nilẹ Yoruba, pẹlu boun atawọn ẹmẹwa ẹ ṣe n fi maaluu jẹ oko awọn agbẹ, to n ba ire-oko wa jẹ. Ọmọ wa kan dako bii eeka mẹẹẹdogun lọdun mẹta sẹyin, awọn ọmọ Wakili si lọọ fi maaluu jẹ oko paki rẹ to fi jẹ pe ọmọ naa ko ri ẹyọ paki kan mu ninu oko naa. A fọlọpaa mu un, ko da awọn ọlọpaa lohun, a si sọ pe ko kuro lori ilẹ wa, niṣe lo ta ku to loun o nibi kan an lọ. A tun pe e lẹjọ, ile-ẹjọ ni ẹnikan o le le ẹnikan kuro nibi kan, ẹ o ri iya ti wọn fi n jẹ wa.
“Tori ẹ lo fi jẹ pe igbesẹ tawọn OPC gbe yii, o dun mọ mi gidi, o si tẹ mi lọrun pẹlu, a ti gbiyanju titi, ta o ri Wakili mu, ti ko si lọ, a waa jaja ri ẹni ba wa ṣi i nidii, a o ni i jẹ ko tun pada sori ilẹ yii mọ, awọn alalẹ ilẹ yii o ni i jẹ ka tun ri Wakili atawọn eeyan ẹ lagbegbe Ibarapa, ki i ṣe Ayetẹ nikan, ni gbogbo agbegbe Ibarapa ati Oke-Ogun pata ni, eegun rẹ ko gbọdọ tun ṣẹ nilẹ yii mọ.
“Wakili ti ko arajẹ ba wa lori ilẹ awọn baba wa. Ẹni to ba n febi paayan, tọhun fẹ keeyan ku ni, awa ta a o niṣe meji ju iṣẹ agbẹ lọ, ẹ wo iye ti wọn n ta apo paki bayii, o ti di ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn naira, baafu ẹ ti di ẹgbẹrun mẹwaa naira, baafu kan pere, awọn Fulani lo sọ wa dẹni ti o ri paki jẹ. O ti ju oṣu meji lọ bayii ti ọpọ agbẹ ti lọ soko gbẹyin.
“Iyẹn lo fi jẹ pe o ya mi lẹnu gidi nigba tẹnikan n ba tiwa jẹ, tawọn ọmọ wa si dide, ti wọn mu onitọhun, ti wọn o lu u, wọn o pa a, wọn fa a le ijọba lọwọ ni, to si yẹ kijọba ṣe ẹtọ lori ẹ, to tun waa jẹ awọn ọmọ waa naa ni wọn ti mọle. Bi wọn ṣe ti awọn ọmọ OPC mọle yẹn ku diẹ kaato, ko tiẹ daa rara. Ọrọ ijọba nigba mi-in, nnkan ni.”
Ọba Okeniyi tun sọ pe awọn lade-lade nilẹ Ibarapa lo dunnu si bi wọn ṣe mu Wakili. O lawọn ọba naa si n kọminu si bijọba to wa lode yii ṣe n dọgbọn huwa bii ẹni n ṣatilẹyin fawọn Fulani ti wọn n ṣe wa ni ṣuta.