Faith Adebọla, Eko
Gbangba dẹkun kedere bẹ ẹ wo fun ogbologboo adigunjale kan, Ikechukwu Ofili, tọwọ awọn agbofinro ba nipinlẹ Eko lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, iṣẹ ọkada jijigbe loun atawọn kọsitọma ẹ yan laayo, o si jẹwọ pe awọn ti ji ọkada bii aadọrin (70) kọwọ palaba awọn to segi yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọgbẹni Ikechukwu, ọmọ bibi ipinlẹ Anambra, lọwọ ba lagbegbe Ajah, Lẹkki, nijọba ibilẹ Eti-Osa, nipinlẹ Eko, o jẹwọ pe agbegbe Ajah ati Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun loun ti n ṣiṣẹ adigunjale, ṣugbọn Ojule kọkanlelogun, Opopona Balogun, lagbegbe Ijoko-Ota, ni Sango, ipinlẹ Ogun loun n gbe.
Awọn ikọ ọlọpaa STS (Special Tactical Squard) ni wọn fi pampẹ ofin gbe ọkunrin naa, lẹyin tawọn aladuugbo ti ta wọn lolobo ti wọn si ti n fimu finlẹ nipa iṣẹ laabi to n ṣe lagbegbe ọhun.
Okechukwu ṣalaye pe niṣe loun maa n da ọkada toun ba fẹẹ ji gbe duro lori irin, oun aa darukọ ọna to jin fọlọkada naa pe ibẹ loun fẹ ko gbe oun lọ, oun o ni i yọwo iyekiye ti ọlọkada naa ba loun maa gba.
O ni bawọn ṣe n lọ, oun maa maa ba ọlọkada naa sọrọ bii ọrẹ, oun aa si maa bi i ni ibeere lati le mọ iru ẹni to jẹ, to ba si ti gbe oun de ibi ti wọn n lọ, oun maa da a duro pe ko fi nnkan tutu rẹ oungbẹ, ohunkohun ti ọlọkada naa ba loun maa n mu loun maa ra fun un.
Wọn lafurasi ọdaran naa jẹwọ pe nibi tonitọhun ti n mu nnkan lọwọ loun ti maa dọgbọn po egboogi amoorun-kun-ni, Dynamogen, mọ ohun to n mu, o ni egboogi naa lagbara debii pe to ba ti le fẹnu kan an, o maa sun lọ ni, ti tọhun ba si ti le sun pẹnrẹn, oun aa ti palẹmọ ọkada rẹ, ọna oun aa ti jin ki oni nnkan too taji.
Ọkunrin naa tun sọ fun awọn aladuugbo rẹ pe ọkan ninu ikọ amuṣẹṣe (Task Force) tawọn ijọba gba lati maa fi pampẹ ofin mu awọn ọlọkada to rufin loun, o nidii toun fi sọ bẹẹ ni ki wọn ma baa tete fura si bo ṣe n gbe oriṣiiriṣii ọkada wale loorekoore, to si n ta wọn laarin ọjọ kan sikeji.
O tun loun maa n de fila awọn ṣọja, oun si maa n wọ ẹwu awọtẹlẹ wọn nigba mi-in, tabi koun so ankaṣiifu wọn mọ ọrun ọwọ, ko le da bii pe loootọ loun n ṣiṣẹ agbofinro, kia toun ba si ti gbe ọkada toun ji de ile loun ti maa so ami mọ ọn lara pe oun fẹẹ ta a ni (FOR SALE), tawọn eeyan ba si ti ri i pe ṣọja kan lẹni to fẹẹ ta a, oju-ẹsẹ loun ti maa n ri i ta. O loun tun lawọn ti wọn maa n ba oun ṣe risiiti (receipt) awuruju. O loun ti ji to aadọrin ọkada lati bii oṣu mẹfa toun ti bẹrẹ opureṣan yii.
Nigba tiwadii bẹrẹ, wọn lọwọ tun ba awọn kọsitọma to n raja ole lọwọ afurasi ọdaran yii. Lara awọn ti wọn n sọ tẹnu wọn fawọn agbofinro lọwọ ni Panti, Yaba, ni Elija Ojole, ẹni ọdun mẹtalelogun, Paul Ngbede, ẹni ọdun mọkandinlogun ati Usman Ocho, ẹni ọdun mẹrinlelogun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn.