Aadọta miliọnu lawọn ajinigbe fẹẹ gba lori ọmọ mẹta ti wọn ji gbe l’Ondo

Bii aadọta miliọnu naira lawọn ajinigbe ti wọn ji awọn ọmọ mẹta kan gbe l’Ondo n beere fun bayii.

Laarin ilu kan ti wọn n pe ni Owo si Ifọn, nijọba ibilẹ Ọsẹ, ni wọn ti ji awọn ọmọ ọhun gbe pẹlu awọn iya wọn, atawọn eeyan marun un mi-in lopin ọsẹ to kọja.

Ilu kan ti wọn n pe ni lmoru, ni wọn sọ pe wọn n lọ fun ayẹyẹ pataki kan.

Bakan naa la gbọ pe wọn tun ti ji awọn eeyan marun-un kan ti wọn n lọ si Eko jẹẹjẹ wọn gbe laarin ilu kan to n jẹ Ago Asabia, ṣaaju Elegbeka, lojuna Benin si Akurẹ.

ALAROYE gbọ pe nibi ti ọkunrin awakọ kan ti n gbiyanju lati sa mọ wọn lọwọ ni wọn ti yinbọn fun un, to si ku lojuẹsẹ.

Ohun tawọn eeyan agbegbe naa n sọ ni pe latigba ti awọn ẹlẹwọn kan ti raaye sa lọgba ẹwọn ni wahala ijinigbe ti pọ ju lagbegbe ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, sọ pe oun ko ti i gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ lawọn eeyan agbegbe naa ko ti i fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti paapaa.

Tẹ o ba gbagbe, lasiko wahala rogbodiyan SARS lawọn ẹlẹwọn kan raaye sa lọgba ẹwọn, latigba naa lawọn eeyan agbegbe ọhun ti sọ pe gbogbo igba ni wọn n ji eeyan gbe nibẹ

 

Leave a Reply