Aadọta miliọnu lawọn ajinigbe to ji akẹkọọ Fasiti Taraba meji n beere fun

Adewale Adeoye

Miliọnu lọna aadọta Naira (N50M) lawọn ajinigbe kan ti wọn ji akẹkọọ ileewe Fasiti Taraba ‘Federal University’, to wa lagbegbe Wukari, nipinlẹ Taraba, n beere fun ko too di pe wọn maa tu awọn akẹkọọ ọhun silẹ lahaamọ wọn.

Awọn akẹkọọ meji ti wọn wa lahaamọ awọn ajinigbe naa ni Omidan Obianu Elizabeth ati Joshua Sardauna, ti wọn ji gbe ninu ọgba ileewe wọn ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaalẹ ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Alukoro agba ileewe naa, Abilekọ Ashu Agbu, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn ajinigbe naa ti pe, ohun ti wọn sọ ni pe, ‘Ẹni to nile ounjẹ igbalode tawọn ti ji awọn akẹkọọ ileewe naa gbe lawọn fẹẹ ji gbe gan-an, ṣugbọn nigba tawọn ko ba a nibẹ lawọn ṣe kuku ji awọn akẹkọọ ọhun gbe sa lọ lati fi paroko silẹ de e. Miliọnu lọna aadọta Naira lowo tawọn ajinigbe naa n beere fun lọwọ awọn alaṣẹ ileewe ọhun, wọn si tun ṣeleri pe awọn ṣi maa tun pada waa ji ẹni to nile ounjẹ igbalode naa laipẹ yii.

Ṣa o, awọn alaṣẹ ileewe ọhun atawọn akẹkọọ kọọkan ti n lọ kaakiri igberiko, paapaa ju lọ awọn inu igbo to sun mọ ileewe ọhun lati wa awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe yii, ki wọn le gba wọn silẹ lahaamọ awọn ajinigbe naa.

Alukoro ni idaniloju gidi wa pe laipẹ lawọn akẹkọọ naa maa gba ominira.

Leave a Reply