Lẹyin ti baale ile yii pa iyawo ẹ tan loun naa gbe majele jẹ

Adewale Adeoye

Ha-in lọrọ oṣiṣẹ banki kan, Oloogbe Mike Illishebo, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, to pa iyawo rẹ,  Valeria Franco, ẹni ọdun marundinlogoji, ṣi n jẹ fun gbogbo awọn to gbọ ọ. Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni oloogbe naa to n gbe lagbegbe Meanwood Ndeke, niluu Lusaka, lorileede Zambia, fi okun fun iyawo rẹ lọrun pa nitori ọrọ ti ko to nnkan to waye laarin awọn mejeeji. Lẹyin to fokun fun un lọrun tiyẹn ko tete ku lo ba tun fọbẹ aṣooro ọwọ rẹ gun un lẹgbẹẹ ikun, niyẹn ba ku patapata.

ALAROYE gbọ pe lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun maa waye, awọn araale wọn ko mọ pe ọrọ ti wọn jọ n sọ ni bonkẹlẹ laarin ara wọn le dija nla to bẹẹ rara, ṣugbọn kawọn eeyan naa too mọ ohun to n ṣẹlẹ, ọkọ iyawo yii ti mu okun ina kan to wa ninu ile wọn, o fi fun iyawo rẹ lọrun ko ma baa pariwo sita, nigba tiyẹn ko tete gbẹmi-in mi lo ba tun fọbẹ gun un yannayanna nikun.

Lẹyin naa ni ọkọ ọhun ba lọọ gbe majele jẹ, toun naa si ku sinu ile.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Rae Hamoonga, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii, so pe Abilekọ Alice Mapulanga, ẹni ọdun mejilelogoji, to jẹ araale wọn lo waa fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti tawọn si tete lọ sibi iṣẹlẹ ọhun lati fẹsẹ ofin tọ ọrọ naa.

Ninu atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fi sita lo ti sọ pe, ‘‘Ni nnkan bii aago mẹrin kọja iṣẹju marun-un ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ija nla kan waye laarin awọn tọkọ-taya meji kan ti wọn n gbe lagbegbe Meanwood Ndeke, niluu Lusaka, lorileede Zimbabwe, ija naa le debii pe ọkọ ọhun, Oloogbe Illishebo, fi okun ina fun iyawo rẹ lọrun pa, nigba tiyẹn ko si tete ku lo ba gun un yannayanna nikun, tiyẹn si ku patapata. Loju-ẹsẹ ni ọkọ iyawo naa ba tun gbe majele jẹ, toun naa si ku sinu yara wọn.

Nigba ta a maa debẹ, oku iyaale ile ọhun la ba ninu agbara ẹjẹ, lẹyin naa la tun ri oku  Illishebo, toun naa ti ku lẹyin to gbe majele jẹ tan.

Iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun fi han pe ede-aiyede kan lo waye laarin awọn tọkọ-taya ọhun, ti Illishebo si gbẹmi iyawo rẹ.

Wọn ti gbe oku awọn mejeeji lọ si mọṣuari kan to wa nileewosan ijọba agbegbe naa fun ayẹwo.

Leave a Reply