Ojo nla ṣọṣẹ ni Poli Ekiti, ọpọlọpọ nnkan lo bajẹ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Kayeefi nla lo jẹ fun gbogbo eeyan ipinlẹ Ekiti l’Ọjọbọ, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin yii, pẹlu bi ojo nla kan ṣe ba dukia olowo iyebiye jẹ nileewe poli to jẹ ti ijọba apapọ ni Ado-Ekiti.

Ojo naa ti ko rọ ju wakati meji lọ lo ba ọpọlọpọ nnkan jẹ nileewe naa, bo tilẹ jẹ pe ẹmi kankan ko ba iṣẹlẹ naa lọ. Awọn gbọngan nla-nla to wa ni ileewe naa lo ṣi ori wọn sọnu, bakan naa lo tun wo opo ina to wa ninu ọgba naa.

Niṣe lawọn kan n wo ojo ọhun gẹgẹ bii aransi, nitori pe ko rọ de awọn apa ibi kan niluu naa, paapaa ju lọ, ni agbegbe ti ileewe naa wa.

Latigba ti oju to ṣọṣẹ buruku ọhun ti rọ ni ileewe naa ti wa ninu okunkun biribiri, bakan naa ni awọn akẹkọọ kori kilaasi wọ lati kẹkọọ, eyi da ohun gbogbo duro titi di asiko yii.

Ọga agba poli naa, Dokita Temitọpe Alake, sọ lasiko to n mu awọn akọroyin yika awọn ohun to bajẹ ninu ọgba ileewe naa pe o jọ pe wọn ran iji lile to ba ojo naa rin si ileewe naa lati wa ba awọn dukia olowo iyebiye jẹ ni.

Lara awọn ibi ti iji naa ti ṣọṣẹ ni gbọngan nla kan to jẹ ti awọn akẹkọ imọn ẹrọ, ọfiisi awọn olukọ, ibi igbọkọ-si, gbọngan awọn akẹkọọ, ilegbee awọn akẹkọọ ọkunrin ti wọn n pe ni Abuja.

Bakan naa ni iji yii tun fọwọ kan orule gbọngan ibi idaraya, oriko ikẹkọọ imọn idokoowo, ibugbe awọn akẹkọọ obinrin ati awọn gbọngan nla miiran laarin ọgba ileewe naa.

Leave a Reply