Ọpọlọpọ egboogi oloro ti ọmọkunrin yii fẹẹ gbe sọda siluu oyinbo lo ti ya jade lakata NDLEA

Monisọla Saka

Ọwọ ajọ to n gbogun ti tita, rira ati lilo egboogi oloro nilokulo lorilẹ-ede yii, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ ọgbẹni kan, Freeman Charles Ogbonna, to gbe egboogi oloro kokeeni bii idi ọgọrin ti wọn ti pọn pelebe pelebe, ni papakọ ofurufu ilu Eko.

Gẹgẹ bi Fẹmi Babafẹmi ti i ṣe agbẹnusọ ajọ yii ṣe sọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, o ni lati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ọwọ ti tẹ ọkunrin naa.

Lasiko ti Ogbonna fẹẹ wọ baaluu to n lọ si Delhi, lorilẹ-ede India ni wọn ti mu un. Bakan naa ni wọn tun ka ayederu iwe irinna ati idanimọ orilẹ-ede Liberia, pẹlu orukọ to yatọ si eyi to n jẹ, iyẹn Carr Bismark mọ ọn lọwọ.

Babafẹmi ni, “Lasiko ti wọn lọọ ṣe ayẹwo to n yẹ ara eeyan wo lati ori de eekanna ẹsẹ ninu papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport, Ikẹja, nipinlẹ Eko, ni wọn ri i pe egboogi oloro n bẹ ninu ara ẹ.

Ninu iwadii ti wọn ṣe ni wọn ti ri i pe orukọ to n jẹ gangan ni Freeman Charles Ogbonna.

“Loju-ẹsẹ naa ni wọn ti da a duro si akata NDLEA, ki wọn le maa ṣakiyesi rẹ. Ko pẹ rara ti ara fi bẹrẹ si i ni ọkunrin yii, to si han lara rẹ pe nnkan ko rọgbọ fun un. Ọpọlọpọ oogun oloro to gbe mi ati eyi ti wọn lo fun un lati di igbẹ fun iwọnba akoko ti yoo fi debi to n lọ ti n ni in lara, o si ti n da gbogbo inu rẹ ru pẹlu.

“Ko pẹ pupọ lẹyin rẹ ni afurasi bẹrẹ si i pòfóló, ki wọn si too ṣẹju pẹu, eebi to lagbara lo tẹle e, ko si pẹ rara to fi bẹrẹ si i ya egboogi oloro yii bii igbẹ. Bo ṣe n bi egboogi oloro ti wọn ti di pẹlẹbẹ pelebe yii naa lo n ya a mọ’gbẹẹ lasiko kan naa.

“Idi ọgọrin kokeeni ni afurasi to ṣalaye pe mọlẹbi oun kan lo mu oun wọ iṣẹ fayawọ egboogi oloro yii ya toun ti eebi. Gbogbo egboogi oloro to ya, to si bi mọ eebi yii jẹ giraamu ẹẹdẹgbẹrun din diẹ (889), laarin ọjọ mẹrin”.

Babafẹmi ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira (300,000) ni Ogbonna ni wọn ṣeleri pe wọn maa fun oun toun ba le gbe egboogi oloro to fẹrẹ mu ẹmi ẹ lọ yii de orilẹ-ede India layọ.

Ninu otẹẹli kan to wa lagbegbe Ipodo, Ikẹja, nipinlẹ Eko, lo sọ pe awọn ti wọn ran oun niṣẹ yii ti gbe egboogi oloro yii fun oun lati gbe mi.

Alukoro yii ni afurasi ọhun ṣi wa lakata NDLEA, ti iwadii si n lọ lọwọ lati mu awọn to ran an niṣẹ yii.

Leave a Reply