Ibọn onike lawọn eleyii fi n jale tọwọ fi tẹ wọn

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe Isọkoko, ni Agege, nipinlẹ Eko, lawọn gende meji kan, Kyari Idris, ẹni ogun ọdun, ati Abubarkar Salisu, ẹni ọdun mejidinlogun wa. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn n lo ibọn onike ti i ṣe ibọn awọn ọmọde lati maa fi ja awọn araalu lole.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa agbegbe Isọkoko, ti wọn n ṣiṣẹ lagbegbe Reluwee, da ọkada tawọn ọdaran ọhun wa lori rẹ duro, wọn fẹẹ yẹ ẹ wo boya wọn lẹbọ lẹru. Ṣugbọn kaka ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa, niṣe ni wọn gbeja ko wọn loju, wọn lawọn ko ni i gba ki wọn yẹ ọkada awọn wo rara. Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki awọn ọlọpaa naa pe fun iranlọwọ awọn ẹlẹgbẹ wọn. Lẹyin ọpọlọpọ wahala, ọwọ tẹ wọn, wọn si ba ibọn onike meji labẹ ọkada wọn. Eyi lo mu ki wọn fọwọ ofin mu wọn ju sahaamọ  loju-ẹsẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ Kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ọdọ awọn ọlọpaa ti wọn wa ni wọn ti jẹwọ ohun ti wọn n fi ibọn onike meji ti wọn ba lọwọ wọn ṣe.

Alukoro ni laipẹ yii lawọn maa too foju wọn bale-ẹjọ, ki wọn le jiya ẹṣẹ wọn

 

Leave a Reply