Nitori foonu, ṣọja ati olotẹẹli fiya jẹ ọmọkunrin yii titi to fi ku

Monisọla Saka

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Imo ti tẹ Ọgbẹni Ibe Obasi, ọkunrin to ni ile itura Our Guest Hotel, to wa niluu Umulogho, ijọba ibilẹ Obowo, nipinlẹ naa, nitori ẹsun ipaniyan.

Ọkan lara awọn to n ba Obasi ṣiṣẹ ni otẹẹli rẹ, Ebuka Nwaneri, ni wọn ni ọkunrin to ni ile itura yii ati ṣọja kan fiya jẹ titi to fi ku latari ẹsun foonu ti wọn lo ji gbe.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni iṣẹlẹ yii waye, amọ to jẹ oku Ebuka ni wọn ba laaarọ ọjọ keji, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ninu ile jẹnẹretọ ti wọn ti i pa mọ lẹyin ti wọn fiya jẹ ẹ tan.

Foonu ọkunrin ologun ti wọn ko darukọ ẹ ni wọn ni Ebuka ji, nibi ti ṣọja yii ti n ṣaaji rẹ lasiko to waa gbafẹ nileetura naa.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ri okodoro ọrọ lori pe Ebuka gangan lo ji foonu naa gbe, ohun to mu wọn dunran ole yii mọ ọn ni pe wọn ni o ti kọkọ wa sibi iṣẹ tẹlẹ, o si ti pada lọ sile ko too tun pada wa.

Nitori idi eyi ni Ọgbẹni Obasi, ṣọja to ni foonu, ati ọkunrin kan toun naa ti sa lọ, ṣe wọ ọ lọ si ẹyinkule ileetura naa, nibi ti wọn ti fiya nla jẹ ẹ, ti wọn si lọọ ti i mọ’nu ile ti ẹrọ jẹnẹretọ otẹẹli naa wa. Ooru ati eefi ile jẹnẹretọ ọhun, ati iya ti wọn ti fi jẹ ẹ tẹlẹ, ni wọn lo pada pa ọmọkunrin yii.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Imo, Henry Okoye, fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ yii.

O ni, “Teṣan ọlọpaa Obowo ti fi panpẹ ofin gbe oludasilẹ otẹẹli Our Guest House, to wa lagbegbe Umulogho, nijọba ibilẹ Obowo, iyẹn Ọgbẹni Ibe Obasi, ẹni ọdun mejidinlogoji (38), ti wọn lo lọwọ ninu iku Ebuka Udemba, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25), ọmọ bibi ilu Umuokpa, nijọba ibilẹ Obowo, nipinlẹ Imo.

“Iwadii ta a ṣe fi han pe afurasi atawọn meji mi-in ti wọn ti sa lọ bayii fiya gidi jẹ oloogbe, ti wọn si tun ti i pa mọ’nu ile jẹnẹretọ otẹẹli naa, nibi ti eefin pada pa a si, pẹlu ẹsun pe o ji foonu ọkan lara awọn onibaara wọn.

“Wọn ti gbe afurasi tọwọ tẹ lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii iwa ọdaran, (SCID), to wa niluu Owerri, olu ilu ipinlẹ Imo. Gbogbo awọn ọrọ to le ran iwadii yii lọwọ ni afurasi ti fun wa, lati le mu ko rọrun fawọn agbofinro to n ṣiṣẹ iwadii yii lọwọ.

Bakan naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Imo, CP Aboki Danjuma, to ba awọn mọlẹbi oloogbe daro bu ẹnu atẹ lu iwa ọdaju bẹẹ, ati fifi idajọ sọwọ ara ẹni”.

Nitori iṣẹlẹ yii lo mu ki awọn ọdọ ilu Umulogho, fọn si titi lati fẹhonu han lori iku ọkan lara wọn ti wọn pa ni ipa oro.

Aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ni wọn ri oku oloogbe ninu oko ẹgẹ to wa lẹgbẹẹ otẹẹli naa, nibi tawọn afurasi ju u si lẹyin to ku tan.

Ibinu eyi ni wọn lo mu kawọn ọdọ sun apa kan ile itura naa, pẹlu ikilọ pe ti iya to tọ ko ba jẹ gbogbo awọn ti wọn pa Ebuka, gbogbo otẹẹli naa lawọn yoo jo kanlẹ, bẹẹ lawọn yoo fiya jẹ ọkunrin to ni ile itura naa.

Leave a Reply