Ijọba apapọ kede ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọruu gẹgẹ bii isinmi ọdun itunu aawẹ

Adewale Adeoye

Ijọba orileede Naijiria ti kede ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, ati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, gẹgẹ bii ayajọ ọjọ isinmi fun ti ayẹyẹ itunu aawẹ.

Akọwe agba fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle, Abilekọ Aishetu Ndayako, to gba ẹnu Ọgbẹni Olubunmi Tunji-Ojo, ti i ṣe minisita sọrọ sọ ọ di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹrin, ọdun yii, pe isinmi ọlọjọ meji maa wa fawọn eeyan orileede yii lati fi wa pẹlu awọn ẹbi wọn gbogbo fun ti ajọdun itunu aawẹ.

Atẹjade ti minisita ọhun fi sita lori isinmi ọhun lo ti ki gbogbo awọn ẹlẹsin Musulumi ododo ti wọn n gbaawẹ ninu oṣu Ramadan, pẹlu inu kan pe ẹmi wọn aa rẹyin oṣu naa pẹlu alaafia ara.

O waa rọ wọn pe ki wọn ṣamulo gbogbo ohun daadaa ti wọn kọ lasiko aawẹ ọhun lati maa fi huwa lawujọ lẹyin oṣu mimọ naa, ki wọn si jẹ awokọṣe daadaa laarin ilu gẹgẹ bi iwe mimọ ṣe tọka si i fun wọn.

Bakan naa lo ni ki awọn araalu maa wa ni irẹpọ nigba gbogbo, ki wọn si maa gbadura fawọn to n ṣakooso ijọba orileede Naijiria.

 

Leave a Reply