Eyi lawọn ohun to yẹ ki ẹ mọ nipa afikun owo ina mọnamọna

Monisọla Saka

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ ina mọnamọna lorilẹ-ede yii, Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC), ti kede awọn ti ọrọ owo to gori ina ijọba to ṣẹṣẹ waye yii kan gbọngbọn.

Gẹgẹ bi Musiliu Oseni, ti i ṣe igbakeji olori ajọ NERC ṣe sọ, ipele marun-un ni wọn pin awọn onibaara ina mọnamọna si, amọ to jẹ awọn isọri kan ni ọrọ afikun owo yii ba.

Ipele marun-un yii ni Band A, B, C, D, ati E. Igba Naira ati marundinlọgbọn (#225), ni kilowaati mita yoo ma ka fun wakati kan, dipo Naira mẹrindinlaaadọrin (#66) to wa tẹlẹ, fawọn to wa ni ipele A, iyẹn (Band A).

Ileeṣẹ yii fi araalu lọkan balẹ pe awọn onibaara to wa nipele Band A nikan ni owo ina wọn gbera soke si ti atẹyinwa.

Bakan naa ni ileeṣẹ yii tun pa a laṣẹ fawọn ẹka ileeṣẹ wọn ti wọn ti n pin ina lati ṣe agbekalẹ ikanni kan si ori ayelujara wọn ko too di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, eyi ti yoo fawọn onibaara lanfaani lati mọ ipele ti wọn ba wa. Eyi ni wọn ni yoo ṣee ṣe fawọn araalu, ni kete ti wọn ba ti tẹ nọmba mita wọn tabi eyi ti wọn fi n sanwo banki si i.

Fun awọn araalu to ba fẹẹ mọ ipele tawọn wa ṣaaju ikanni ayelujara NERC ti wọn fẹẹ ṣe, awọn Band A, ti afikun gun ori owo ina wọn lawọn onibaara ti wọn n jẹ igbadun ina mọnamọna oni ogun wakati si wakati mẹrinlelogun (20-24hrs), o waa kere tan, ogun wakati lojumọ.

Ipele keji, ti i ṣe Band B, ni awọn ti wọn n lo ina laarin wakati mẹrindinlogun si ogun, leyii ti ko din ni wakati mẹrindinlogun (16hours), lojumọ kan.

O kere tan wakati mejila, tabi wakati mejila si mẹrindinlogun, lawọn onibaara to wa ni Band C fi n lo ina lojumọ.

Nigba tawọn to wa ni Band D n gbadun ina laarin wakati mẹjọ si mejila, awọn ipele to kẹyin, iyẹn Band E, ni akoko ti wọn fi n lo ina kere ju lọ, iyẹn laarin wakati mẹrin si mẹjọ lọjọ kan.

Ninu agbegbe bii irinwo ati mọkanlelọgọrin (481) ti awọn onibaara to jẹ Band A, ti ọrọ owo ina tuntun yii yoo kan ni Abuja ti lewaju pẹlu agbegbe mẹtadinlaaadọfa (107), Jos Electricity, nipinlẹ Plateau, jẹ mẹrinlelọgọta (64), nipinlẹ Eko, Ikẹja Electricity Distribution Company, tẹle e pẹlu marundinlaaadọta (45), ileeṣẹ mọnamọna Benin ati Enugu jẹ mẹrinlelogoji (44), ti Port Harcourt, nipinlẹ Rivers ati ti Kano jẹ mẹtalelogoji (43). Ibadan Electricity jẹ ọgbọn (30), Kaduna jẹ mẹẹẹdọgbọn (25), nigba ti Eko Electricity Distribution Company (EKEDC), nipinlẹ Eko si ni onibaara mọkanlelogun (21), ni ori mita Band A wọn.

Ileeṣẹ NERC tun fi araalu lọkan balẹ pe gbogbo awọn onibaara ti wọn n gbe owo ina to ju eyi to yẹ ki wọn san lọ fun lawọn yoo da owo wọn pada pẹlu bonọọsi ina (energy token), o pẹ tan, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ mọnamọna ti yanju awuyewuye yoowu to le tibi mimọ ipele ti onibaara kọọkan wa, sibẹ, o dara ki awọn ti owo ina wọn ba ga ju bo ṣe yẹ lọ tabi awọn ti wọn n bẹru pe ileeṣẹ mọnamọna le ṣafikun owo ina tawọn naa lai fi ti ipele tawọn wa ṣe, gba ori ayelujara wọn lọ lati mọ ipele ti wọn wa daju.

Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ina mọnamọna, NERC, buwọ lu afikun owo ina fawọn onibaara wọn to wa nipele Band A.

Gẹgẹ bi Minisita fọrọ ina lorilẹ-ede yii, Bayọ Adelabu, ṣe sọ, o ni nitori owo iranwọ ina tijọba apapọ yọ ati owo dọla to gbẹnu soke, ni afikun ṣe de ba owo ina awọn onibaara to wa ni Band A. O ni ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ni ọrọ owo ina tuntun yii ko ni i kan, nitori awọn to wa nipele A yii ko ju ida mẹẹẹdogun ninu ọgọrun-un gbogbo awọn to n lo ina lorilẹ-ede yii lọ.

Leave a Reply