‘’Iya gidi ni yoo jẹ ọlọpaa to ba yẹ foonu araalu wo loju titi’’

Monisọla Saka

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, ẹka ti ipinlẹ Edo, ti ṣe e leewọ fawọn agbofinro wọn lati maa yẹ foonu araalu wo, paapaa ju lọ awọn ọlọpaa to n duro nirona lati yẹ mọto ati ero to n lọ wo, atawọn to n ṣe paturoolu kiri igboro.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni SP Chidi Nwabuzor, ti i ṣe alukooro ọlọpaa nipinlẹ naa fi atẹjade yii sita lorukọ kọmiṣanna ipinlẹ Edo.

Kọmiṣanna ipinlẹ Edo, CP Funshọ Adegboye, ni Nwabuzor ṣalaye pe o ti gba awọn agbofinro ipinlẹ naa niyanju lati ma ṣe gbidanwo pe wọn yoo maa tu foonu onifoonu wo gẹgẹ bii aṣẹ to ti oke, lati ọdọ ọga ọlọpaa patapata, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, wa.

Ninu atẹjade ọhun lo ti ni, “Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Edo, CP Funshọ Adegboye, ti tun mẹnu ba aṣẹ ti ọga ọlọpaa patapata nilẹ Naijiria, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, pa lori bi wọn ṣe fofin de titu foonu araalu wo lai jẹ pe ile-ẹjọ pa a laṣẹ pe ki wọn ṣe bẹẹ latari iwadii”.

Nwabuzor ni ikilọ nla ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Edo ṣe fawọn ọmọ abẹ ẹ gẹgẹ bi wọn ṣe pa gbogbo ọga ọlọpaa agbegbe ati ipinlẹ kọọkan laṣẹ lati oke wa, ati pe eyikeyii ninu wọn ti ko ba dẹyin ninu iwa ti ko bofin iṣẹ yii mu yoo da ara rẹ lẹbi.

Tẹ o ba gbagbe, igba akọkọ kọ niyi ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo maa pe araalu si akiyesi pe ọlọpaa kankan ko lẹtọọ lati da wọn duro nirona lati maa yẹ foonu wọn wo.

Bẹẹ ni wọn ti kilọ fawọn agbofinro naa laimọye igba pe dukia adani eeyan ni foonu, wọn ko si lẹtọọ lati ṣadeede da eeyan duro ki wọn maa tu gbogbo ori foonu wọn wo. Ọlọpaa to ba dan iru eleyii wo ti ọwọ ba tẹ ẹ, iya to tọ ni wọn ni yoo jẹ labẹ ofin.

Leave a Reply