Wọn ti mu Pasitọ James to lu ọmọ ijọ rẹ ni jibiti owo nla n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commision’ (EFCC), ẹka tipinlẹ Kwara ti tẹ ojiṣẹ Ọlọrun kan, Pasitọ Adeniyi Abiọdun James, lẹyin ti ọmọ ijọ rẹ, Oluwọle Babarinde, lọọ fẹjọ rẹ sun pe o lu oun ni jibiti owo nla.

ALAROYE gbọ pe Oluwọle Babarinde, lo lọọ fẹjọ pasitọ naa sun lọdọ awọn EFCC pe o lu oun ni jibiti owo to le ni miliọnu mẹta Naira, eyi to ni oun fẹẹ lo lati fi ba oun gba iwe irinna lọ si orile-ede Canada.

Ọkunrin ọhun ṣalaye fun EFCC pe Pasitọ James lo pe oun jade nibi eto kan ti wọn n ṣe nile-ijọsin CAC to wa niluu Ilọrin, to si ni oun riran si oun pe oun yoo rinrin-ajo lọ siluu oyinbo, ati pe awọn yoo dijọ ṣọrọ to ba ya.

O ni lẹyin eyi ni pasitọ beere pe orile-ede wo lo wu oun lati lọ, nitori pe oun mọ ẹnikan nipinlẹ Eko ti yoo ba a pari gbogbo eto, Babarinde loun sọ pe orile-ede Canada ni oun fẹẹ lọ. Ọkunrin yii ni lati ọdun 2021 ni pasitọ naa si gba owo gọbọi lọwọ oun lati fi ba oun ṣeto irinna lọ si Canada, lai mọ pe onijibiti ni.

Babarinde ni ṣe loun lọọ ta ọpọ ninu awọn dukia oun, ki owo le pe lati fi gba iwe irinna naa, toun si ko owo to sun mọ miliọnu mẹrin Naira le pasitọ lọwọ, ṣugbọn nigba toun reti titi, toun si duro fun igba pipẹ lai ri esi kankan ni oun too gbe ẹsun ọhun wa si ọfiisi ajọ EFCC nitori gbogbo igbiyanju oun lati gba owo naa pada lo ja si pabo.

EFCC ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii awọn yoo foju Pasitọ ba ile-ẹjọ.

Leave a Reply