O ma ṣe o, ọkọ akoyọyọ tẹ ọmọ iya meji pa l’Ọrẹ

 Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Tẹgbọn taburo kan la gbọ pe ọkọ akoyọyọ tẹ pa niluu Ọrẹ, n’ijọba ibilẹ Odigbo, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Awọn ọmọ iya meji ọhun ni wọn ni ọkọ tipa tẹ pa lori ọkada Haojue Suzuki, ti wọn gun lagbegbe kan ti wọn n pe ni Idi Mangoro, eyi to wa loju ọna Ọrẹ si ilu Okitipupa.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ẹnikan to wa nitosi lasiko ti ijamba ọhun waye pe igunkugun tawọn mejeeji gun ọkada lai fi ti oju ọna marosẹ ti wọn wa ṣe lo ṣokunfa bi wọn ṣe funra wọn lọọ ko si abẹ ọkọ akoyọyọ to n lọ jẹẹjẹ ẹ loju loju ọna tirẹ.

O ni lọgan ti ijamba ọhun waye tan ni awakọ tipa naa ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ, to si tete sa kuro nibi iṣẹlẹ naa nitori ibẹru itu tawọn eeyan le fi i pa.

Ọkọ rẹ nikan lawọn ọlọpaa ri wọ lọ si tesan wọn lẹyin ti wọn ko oku awọn mejeeji ti ọkọ tẹ pa lọ si mọṣuari ile-iwosan kan to wa l’Okitipupa.

 

Leave a Reply