Aarẹ Buhari n lọ sibi ipade kan ni  London, yoo fẹsẹ kan ya sọsibitu ẹ

Faith Adebọla

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe Aarẹ orileede wa, Muhammadu Buhari, yoo gbera lọ si London lonii ọjọ Aje ti i ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje yii.

Atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, eyi ti Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, fọwọ si lo ti ṣalaye pe Buhari Buhari yoo tẹkọ leti lọ si orileede United Kingdom, lati kopa ninu ipade kan to ni i ṣe pẹlu ṣiṣe onigbọwọ fun eto ẹkọ lagbaaye ti wọn pe ni (Global Education Summit on Financing Global Patnership fpor Education)

Ipade ọhun to ni Olori ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson, ati Aarẹ orileede Kenya, Uhru Kenyata, ni yoo gbalejo rẹ lo ni awọn aarẹ orileede, awọn alẹnulọrọ atawọn ọdọ ni yoo kopa ninu rẹ lati ṣaṣaro lori ọna lati mu ayipada ba eto ẹkọ ni awọn orileede ti ajọṣepọ yii ti n waye nipa ṣiṣẹ amulo awọn ohun to le ṣanfaani fun ara wọn lati ara awọn orileede yii.

Bakan naa lo ni eto yii yoo fun awọn adari yii ni anfaani lati ṣe ipinnu ati ẹjẹ lati ṣatilẹyin fun eto yii laarin ọdun marun-un, eyi ti yoo fun wọn lanfaani lati mu ayipada ba eto ẹkọ ni awọn orileede bii aadọrun-un ti ajọṣe ti jọ wa.

Lẹyin ipade yii ni wọn ni Aarẹ Buhari yoo tun lo ọjọ diẹ lati fi ṣayẹwo ara rẹ nileewosan. Ọṣẹ keji, ninu oṣu kẹjọ, nireti wa pe yoo pada de.

Leave a Reply