Aarẹ Buhari ti sọrọ o, o ni ki gbogbo ọmọ Naijiria ni suuru

Latari iṣẹlẹ ipaniyan to ṣẹle ni Lẹkki, niluu Eko, ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Aarẹ Buhari ti ni ki awọn aaraalu ṣe suuru pẹlu ijọba, pẹlu bi awọn ṣe n gbiyanju lati ṣe atunṣe si ileeṣẹ ọlọpaa ni Naijiria.

Wẹsidee, Ọjọruu, ọsẹ yii, lo sọrọ naa nipasẹ Oludamọran rẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina. Ọkunrin naa ni ijọba ti n ṣapa lati wa ọna abayọ si atunṣe ileesẹ ọlọpaa.

O ni eyi lo fa a to fi jẹ pe bii ipinlẹ mẹtala lo ti ṣe idasilẹ igbimọ ti yoo gbọ ẹjọ to ba ni i ṣe pẹlu ifiyajẹni awọn ọlọpaa lati fi awọn to ba ṣẹ sofin jofin.

Lara atunṣe to ni ijọba tun ṣe ni ṣisẹ afikun si eto isuna ileesẹ ọlọpaa, ti ijọba si tun gbe owo jade fun idasilẹ ati amojuto ọlọpaa agbegbe.

Bakan naa ni Aarẹ fọwọ si fifofin de SARS kaakiri ilẹ wa.

2 thoughts on “Aarẹ Buhari ti sọrọ o, o ni ki gbogbo ọmọ Naijiria ni suuru

  1. Se nigbati o pe iye oku eyan ti won fe lo ni won sese roro so, abi wonran wonran bi omo ku lowo aditi ti won nwi yi le da emi awon ti o ku pada si aye, aba temi ni wipe ki buari kowe fi ipo re sile. Ire o

Leave a Reply