Jọkẹ Amọri
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ile-ẹjọ giga kan to jokoo niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, da ẹbẹ Adajọ agba nilẹ wa to tun jẹ minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami (SAN), to pe pe ki ile-ẹjọ ma ṣe gbọ ẹjọ ti ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho pe ijọba apapọ nu, wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ.
Igboho lo pe ijọba apapọ lẹjọ, to si beere fun ẹẹdẹgbẹta biliọnu. O rọ ile-ẹjọ pe ki wọn paṣẹ pe titẹ ẹtọ ẹni loju ni bi awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe ya wọnu ile oun lọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, ti wọn si pa eeyan meji, ti wọn tun ba dukia oun jẹ, ti wọn tun ko awọn ọmọlẹyin rẹ bii mejila lọ sọdọ wọn.
Ṣugbọn adajọ agba nilẹ wa yii sọ pe ile-ẹjọ ko le ka pe awọn ọtẹlẹmuyẹ wọle rẹ si titẹ ẹtọ ẹni loju lati beere fun awọn ẹtọ kan. Bẹẹ lo ni wọn ko le ka awọn ẹri to ko silẹ lasiko ti awọn ọtẹlẹmuyẹ wọle rẹ bii ẹsibiiti lai pe awọn ẹlẹrii atawọn igbesẹ mi-in.
Yatọ si eyi, Malami ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ ko lagbara lati gbọ awọn ẹjọ naa.
O waa bẹbẹ pe ki wọn fun oun laaye si i pe ki oun le ko awọn iwe ipẹjọ mi-in jọ ni itẹsiwaju ẹjọ to pe pe ki wọn ma gbọ ẹjọ naa. Awọn agbẹjọro bii mẹwaa lo waa ṣoju Malami nile-ẹjọ giga naa. Abdulahi Abubakar lo ṣaaju wọn.
Ṣugbọn Agbẹjọro agba Igboho, Oloye Yọmi Aliyu (SAN) ti ta ko ẹbẹ yii, o ni bii ifakoko ṣofo lasan ni igbesẹ yii, nitori ọjọ marun-un ni ile-ẹjọ fi aaye silẹ lati fesi lori awọn ẹsun naa, nitori o ni i ṣẹ pẹlu titẹ ẹtọ ọmọniyan loju labẹ ofin.
Lẹyin ti Adajọ Akinọla gbọ ẹjọ awọn igun mejeeji, o gba ẹbẹ Malami lati sun ọjọ naa siwaju lati tun ko awọn iwe kan silẹ, o si faini rẹ ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira fun igbesẹ yii.
Lẹyin naa lo sun ẹjọ ọhun si ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii.