Adajọ ko gba ẹbẹ Udom to gun ọrẹ rẹ pa, wọn ju u sẹwọn Kirikiri

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Oyindamọla Ọgala, tile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, ni wọn wọ Ọgbẹni Emmanuel Udom, to gun ọrẹ rẹ pa ba. Ẹsun ipaniyan ati iwa ọdaran ni Agbefọba, Ọgbẹni Ọla Azeez, to foju olujẹjọ bale-ẹjọ fi kan an ni kootu.

ALAROYE gbọ pe ọrọ kekere kan lo dija silẹ laarin Udom ati Oloogbe Moses Joseph, lọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, niluu Igando, nipinlẹ Eko. Kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Udom ti fọbẹ gun ẹni keji rẹ ti wọn jọ n ja pa patapata. Latigba naa si lẹjọ rẹ ti wa ni kootu, ko too di pe wọn ṣẹjọ rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Nigba too maa sọrọ, olujẹjọ loun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti agbefọba fi kan oun rara.

Adajọ ile-ejọ ọhun ni ki wọn da Udom pada sọgba ẹwọn Kirikiri to wa niluu Eko, lẹyin eyi lo sun igbẹjọ rẹ si ọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii.

 

Leave a Reply