Opin aye de, pasitọ atawọn ọmo ijọ rẹ lọọ digunjale, mọto olowo nla ni wọn ji gbe

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn agbofinro agbegbe kan lorileede South Africa, ni Pasitọ Lincoln Tichaona, ẹni ọdun mọkandinlogun, atawọn ọmọ ijọ rẹ meji, Ọgbẹni Chigwasa Innocent, ẹni ogoji ọdun, ati Ọgbẹni Johannes Matema, ẹni ọdun mejidinlọgbọn wa bayii. Ẹsun pe wọn lẹdi apo pọ lati lọ sorileede Zimbabwe, lati lọọ ji mọto ayọkẹlẹ Nissan Atlas kan lọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii ni wọn fi kan wọn.

ALAROYE gbọ pe gbajumọ ni pasitọ ọhun, o si maa n sọ asọtẹlẹ gbankọgbi nipa ohun to maa ṣẹlẹ lawọn orileede kaakiri agbaye.  O gbajumọ daadaa laarin ilu to bẹẹ gẹ to fi lọmọ ijọ to pọ daadaa lagbegbe to ni ṣọọṣi si ọhun.

Ṣugbọn boya iṣẹ eṣu lo fa a to fi gbera kuro niluu, rẹ to si lọ silẹ Zimbabwe, lati lọọ ji mọto ọhun gbe. Leyin to ji i gbe tan lo gbe e wale, ile ọkan lara awọn alabaaṣiṣẹpọ rẹ kan ni pasitọ si tọju mọto ọhun si, ti wọn si n wa onibaara ti wọn maa ta a fun. Ko pẹ rara tawọn ọlọpaa orileede Zimbabwe fi tọpasẹ mọto ọhun wa sile ti wọn gbe e pamọ si, nitori pe ẹrọ kan wa ninu mọto ọhun to le jẹ ki wọn mọ ibi ti wọn gbe e pamọ si.

Wọn gba pasitọ ọhun atawọn ọmọ ijọ rẹ meji ọhun mu, wọn si da sẹria fun un nita gbangba. Lẹyin eyi ni wọn fa a le ọlọpaa agbegbe naa lọwọ, wọn si wọ mọto ọhun pada sọdọ ẹni to ni i lorileede Zimbabwe.

 

Leave a Reply