Nitori ọrọ ti ko to nnkan, ọrẹkunrin yii pa afẹsọna rẹ danu

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ, ọdọ awọn agbofinro agbegbe Githurai 44, niluu Nairobi, orileede Kenya, ni Ọgbẹni Clinton Mwangi, to gun ọrẹbinrin rẹ, Oloogbe Grace Wangari, ẹni ọdun mẹrinlelogun pa wa.

ALAROYE gbọ pe ede aiyede kekere kan lo waye laarin awọn ololufẹ meji ọhun laipẹ yii, ohun tawọn eeyan si maa ri lẹyin eleyii ni pe Clinton ti i ṣe ọkọ iyawo ti yọ ọbẹ aṣooro ọwọ re jade, o si fi gun ọrẹbinrin rẹ yii yanna-yanna lẹgbẹẹ ikun, titi to fi ku sinu ile lọjọ ọhun.

Ariwo buruku kan tawọn araduugbo ibi ti wọn n gbe gbọ ni wọn fi sare lọ sibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn maa fi debẹ, wọn ti ba Oloogbe Grace ninu agbara ẹjẹ rẹ. Wọn sare gbe e digba-digba lọ sileewosan ijọba agbegbe naa fun itọju, ṣugbọn nigba ti wọn fi maa gbe e debẹ awọn dokita sọ pe oku Oloogbe Grace ni wọn gbe wa sileewosan awọn. Wọn ni apọju ẹjẹ to danu lara rẹ lo ṣokunfa iku rẹ lojiji.

Ọgbẹni Njeri Wa Migwi, to jẹ ajafẹtọọ-ọmọniyan lagbegbe ọhun to gbe ọrọ ọhun sori ayelujaye rẹ lo lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa teṣan Kiambu leti, tawọn yẹn si sare lọọ fọwọ ofin mu ọmọkunrin yii nile rẹ, ko ma baa sa lọ.

Alukoro eto iroyin fun ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe naa ti sọ pe awọn maa too foju  Clinton Mwangi bale-ẹjọ lori ohun to ṣe yii, ti yoo si jiya to tọ si i labẹ ofin.

Leave a Reply