Iyawo mi ti gba nnkan mi-in m’ẹsin, ko ṣetọju emi atawọn ọmọ mọ ninu ile-Bakari

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Doocivir Yawe, tile-ẹjọ kọkọ-kọko kan to wa lagbegbe Nyanya, niluu Abuja, ti i ṣe olu ilu ilẹ wa, lawọn tọkọ-taya kan gbẹjọ ara wọn lọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Ọgbẹni Aku Bakari, ti i ṣe oṣiṣẹ ijọba agbegbe naa lo lọọ fẹjọ iyawo rẹ, Abilekọ Mary Bakari, sun. Ohun to si tori ẹ lọ si kootu ni pe ki ile-ẹjọ ọhun tu igbeyawo to wa laarin awọn mejeeji ka, ki kaluku awọn si maa lọọ jẹẹjẹ ẹ.

Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe, ‘‘Oluwa mi, ko sohun meji to jẹ ki n fẹẹ kọ iyawo mi yii ju pe ki i ṣe ojuṣe rẹ ninu ile mọ rara, ṣọọṣi lo maa n lọ nigba gbogbo, ki i bikita boya emi ti mo jẹ ọkọ rẹ jẹun ninu ile tabi mi o jẹun. Ki i ṣetọju awọn ọmọ rẹ mọ rara. Ṣe laa sọ pe iṣẹ Oluwa toun ṣẹṣẹ gba ni ṣọọṣi toun n lọ ko faaye silẹ foun rara mọ. Bẹẹ ki i ṣe ṣọọṣi ti idile wa n lọ tẹlẹ lo n lọ bayii. Mi o mọ ẹni to pe e si ṣọọṣi ọhun to fi waa jẹ pe igba gbogbo lo n gbọrọ ṣọọṣi lori bayii.

Igba miiran wa ti iyawo mi aa lọ si iṣọ oru ni ṣọọṣi rẹ ọhun lati ọjọ Ẹti, Furaidee, to si jẹ pe o di ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ keji, ko too pada de. Ti mo ba bi i leere pe ṣe ṣọọṣi naa lo ti n bọ ṣa, ko ni i da mi lohun, gbogbo iwa rẹ pata lo ti yatọ gedegede sigba ta a kọkọ fẹra wa.

‘‘Mi o tiẹ le ranti igba ta a jọ sun nile gẹgẹ bii tọkọ-taya mọ. Ki i foju silẹ fun mi mọ ninu ile lati ba a ni ajọṣepọ. Bi mo ba fọwọ kan an laarin oru bayii, ṣe lo maa jagbe mọ mi, o le ni oun n gbaawẹ lọwọ. Kẹ ẹ si maa wo o, ọdun 2010 la ti fẹra wa sile, ti Ọlọrun si fọmọ to daa saarin wa, ṣugbọn aipẹ yii lo bẹrẹ iwa palapala ọhun nile, ẹnu mi ko si ka a mọ rara.

‘‘Ki i lo ẹṣọ sara mọ, ṣe lo kan n ṣe radarada kaakiri, bi mo ba si bi i leere pe ki lo de ti ko ṣe lo ẹṣọ sara, aa sọ pe awọn ọmọ eṣu lo n lo ṣeeni ọrun ati yeti. Ni kukuru, Oluwa mi, mi o ṣe mọ o. Ko sifẹẹ kankan laarin wa mọ, ẹnu mi ko ka a. Ẹ tu wa ka.

Ninu ọrọ tiẹ, Abilekọ Mary ni ko soootọ kankan ninu gbogbo ẹsun ti ọkọ oun fi kan oun yii, ṣugbọn o gba pe loootọ loun ti parọ ṣọọṣi toun n lọ tẹlẹ si tuntun bayii.

Adajọ ile-ẹjọ ọhun rọ awọn tọkọ-taya ọhun pe ki wọn ṣe suuru, ki wọn pada lọ sile lati lọọ feegun otolo to ọrọ ija to wa laarin wọn. O sun igbẹjọ si ọgbọnjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Leave a Reply