A ko ni i yi ipinnu wa pada, a ti fofin de lilo ike ijẹun fulẹ-fulẹ ‘take-away’ niluu Eko

Adewale Adeoye

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe ko si ani-ani kankan nibẹ pe awọn ti fofin de ike fulẹ-fulẹ ti wọn n pe ni ‘take-away’ tawọn eeyan maa n lo nile ounjẹ igbalode kaakiri lati fi gbe ounjẹ wa sile ati ni otẹẹli gbogbo ni lilo bayii. Ṣa o, wọn ni nnkan bii ọsẹ mẹta pere lawọn fun gbogbo awọn ileeṣẹ to n ṣe awọn ike ‘take-away’ ọhun lati ta gbogbo eyi ti wọn ti ṣe silẹ jade tan patapat. Bakan naa ni wọn fun awọn ile itaja gbogbo lọsẹ mẹta pere lati ta awọn ọja ohun tan ninu ṣọọbu wọn ko too di pe gbedeke ọhun maa pe.

Kọmiṣanna fun eto ayika ati omi niluu Eko, Ọnarebu Tokunbo Wahab, lo tun tẹ ẹ mọ awọn eeyan leti lasiko ipade pataki kan to waye laarin awọn ileeṣẹ to n ṣe awọn ohun eelo nilẹ wa, ‘Manufacturer Association Of Nigeria’ (MAN), ati aṣoju ijọba ipinlẹ Eko, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii. Nibi ipade ọhun ni awọn aṣoju ẹgbẹ awọn to nileeṣẹ ti wọn ti n ṣe ohun eelo ati aṣoju ẹgbẹ awọn to nile ounjẹ igbalode atawọn to n taja niluu Eko ‘Restaurant And Food Service Proprietor Associations Of Nigeria’ (REFSPAN) ti peju-pese. Kọmiṣanna ọhun ni ọsẹ mẹta pere nijọba ipinlẹ Eko maa fawọn ẹgbẹ yii lati ta gbogbo ọja to wa ninu igba wọn tan patapata.

Awọn olori ẹgbẹ meji ọhun, Ọgbẹni Okpe Sunday, ti ẹgbẹ (MAN), ati Ọgbẹni Kazeem Ọlaoye, to ṣoju ẹgbẹ (REFSPAN) lo rawọ ẹbẹ sijọba Eko pe ko siju aanu wo awọn lori ipinnu rẹ lati fofin de ike ijẹun ‘take away’ ọhun.

Kọmiṣanna ni lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin bayii nijọba ipinlẹ Eko ti kọkọ kede pe wọn ti fofin de ike ọhun, ṣugbọn ti wọn ko gbe igbesẹ kankan lori rẹ titi di asiko yii. O ni ipalara nla gbaa ni ike ọhun n ṣe fun ilera araalu, ipinlẹ Eko ati ayika wa nigba gbogbo, ti ijọba si gbọdọ tete gbe igbesẹ gidi nipa rẹ bayii.

Wahab ni, Nitori ipalara to n mu ba awọn eeyan ilu lawọn ṣe fẹẹ gbe igbesẹ naa, ati pe awọn ko le sọ pe nitori pe awọn kan n ta a tabi ṣe e jade, kawọn waa gboju sẹgbẹẹ kan, eyi ko daa to. Ṣa o, a maa ṣiju aanu wo awọn oniṣowo to n ta awọn ọja ọhun, bakan naa la maa gbe ọrọ awọn to n ṣe ike ‘take-away’ ọhun sita nipa pe a maa sun gbedeke ọjọ ọhun siwaju si i, ko le rọrun fawọn to ni ọja ọhun nile lati tete ta a sita

Leave a Reply