Abiru ki leleyii, awọn Fulani darandaran ji ọlọpaa mẹta gbe lọ pẹlu ibọn ọwọ wọn

Adewale Adeoye

Ni bayii, gbogbo inu igbo ati ibi gbogbo lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ni kawọn ọlọpaa ipinlẹ naa maa wa boya wọn aa ri awọn ọlọpaa mẹta kan tawọn Fulani darandaran kan ji gbe sa lọ pẹlu ibọn ijọba ọwọ wọn. Iṣẹlẹ kayeefi ọhun waye l’Ọjọbọ,  Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lagbegbe ijọba ibilẹ Ughelli, nipinlẹ Delta.

ALAROYE gbọ pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa kan ti wọn n pe ni PMF 51, niluu Oghara, ni wọn pin awọn ọlọpaa ọhun si, ti wọn si n ṣiṣẹ wọn deede. Agbegbe kan ti wọn n pe ni East-West, nijọba ibilẹ Ighelli, ni awọn ọlọpaa mẹfa kan wa lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun maa waye. Lojiji lawọn Fulani darandaran ọhun yọ sawọn agbofinro ọhun, ti wọn si ji awọn mẹta gbe sa lọ ninu wọn pẹlu ibọn Ak-47 to jẹ tijọba to wa lọwọ wọn. Ṣe lawọn yooku wọn sa wọgbẹ, ki awọn Fulani darandaran ọhun ma baa ji awọn naa gbe sa lọ.

Ọkan lara awọn ọga ọlọpaa to wa ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to gba lati sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun sọ pe, ‘‘Awọn ikọ ọlọpaa ẹlẹni mẹfa kan lo n ṣiṣẹ lagbegbe Ughelli-Patani, ibi ti wọn wa ko fi bẹẹ jinna pupọ siluu kan ti wọn n pe ni Ohoro, nijọba ibilẹ Ughelli, nipinlẹ Delta, ko pẹ ni Ọgbẹni Moses Progress, ẹni ọdun mejilelogun, sare waa pe awọn ọlọpaa ọhun pe ki wọn waa ran awọn lọwọ, o ni  awọn Fulani darandaran kan n yọ awọn lẹnu nibi tawọn ti n ṣe etutu labẹ biriiji kan. Ọga ọlọpaa to ṣaaju ikọ ọhun ran awọn mẹta kan lọọ wo ohun to n ṣẹlẹ nibẹ, wọn si gbe ibọn Ak-47 to jẹ tijọba lọwọ. O pẹ diẹ ti wọn ti lọ ti wọn ko pada de, nigba to ya ni awọn ọlọpaa ọhun ba ri Moses to waa pe fun iranlọwọ ọhun lori ọkada to n lọ lẹlẹẹlẹ, wọn da a duro, wọn beere awọn ọlọpaa to tẹle lọ. O ni gbara tawọn debẹ ni awọn Fulani darandaran ọhun kọju ija sawọn, ti wọn si kapa awọn ọlọpaa ọhun.

O ni ẹni ori yọ o dile lọrọ ọhun da. Ṣugbọn awọn agbofinro yii ko jẹ ki Moses lọ, nitori oun lo waa pe fun iranlọwọ awọn ọlọpaa ohun ko too di pe wọn ji wọn gbe bayii.

Ọga ọlọpaa ọhun ni awọn ti bẹrẹ si i wa awọn oniṣẹ ibi ọhun, tawọn si maa fọwọ ofin mu gbogbo wọn laipẹ rara.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta, S.P Bright Edafe, ko gbe ipe rẹ lasiko tawọn oniroyin n pe e lori foonu rẹ.

Leave a Reply