Lẹyin ti wọn lu u bajẹ: Portable olorin figbe bọnu, ṣe o digba ti mo ba ku kẹ ẹ to gbeja mi ni

Adewale Adeoye

Gbajumọ olorin hipọọpu nni, Abeeb Okikiọla, ẹni tawọn eeyan mọ si Portable, ti figbe bọnu nileewosan aladaani kan to ti n gba itọju lọwọ lẹyin tawọn kan lọọ lu u mọlẹ rẹ lalubami, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Igbe to si n pa lori bẹẹdi ti awọn dọkita oniṣegun oyinbon to n tọju rẹ ni pe ṣe o digba ti oun ba ku ko too di pe awọn ọmọ orileede yii yoo sọrọ soke lori bi awọn kan ṣe waa kogun ja oun mọle oun niluu Eko, laipẹ yii.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn kan lọọ lu Portable mọle rẹ, wọn ni o gbowo nla kan lọwọ awọn, to si kọ, ti ko waa kọrin tawọn jọ ni adehun rẹ. Ṣugbọn ohun ti ọba orin zah zu zeh n sọ ni pe ko soootọ ninu ẹsun awuruju gbogbo ti wọn ka soun lẹsẹ naa rara.

Ninu fidio oniṣẹju diẹ to gbe sori ayelujaye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lo ti sọ pe, ‘O ṣe waa jẹ pe awọn to ti di oloogbe nikan lawọn ọmọ ilẹ wa maa n ja fun nigba gbogbo, ko waa sẹnikankan to sọrọ nipa bawọn kan ṣe waa kogun ja mi mọ’nu ile mi laipẹ yii, wọn fẹẹ pa mi, Ọlọrun Ọba nikan ni ko fẹmi mi le wọn lọwọ. Gbogbo ara lo n ro mi bayii, ẹ maa gbadura gidi fun mi o, mi o fẹẹ ku bayii, mo ṣi kere jọjọ lọjọ ori. Ko sẹni kankan to gbeja mi lati igba tawọn eeyan naa ti waa lu mi, mo ni Ọlọrun, bẹ ẹ ba gbeja mi, Ọlọrun aa ja fun mi, o daju daadaa. Bi Ọlọrun ba si wa nipo rẹ, mi o ni i ku bayii. Mi o gbadun ara mi latigba ti wọn ti waa lu mi, ẹri wa pe wọn waa lu mi, ṣugbọn awọn eeyan ko sọrọ, bẹẹ ni wọn ko gbe igbesẹ kankan lori ọrọ ọhun titi di asiko yii. Ọlọrun wa ṣaa o.’

Igbaju-igbamu ni awọn yẹn si fi ṣe Ọmọ Ọlalọmi, ọsibitu lo si balẹ si nibi ti lilu naa buru de lẹyin to bọ lọwọ wọn. Lati ọjọ Aje, Mọnde, ọhun si ni Portable ti n gba abẹrẹ pẹlu omi nileewesan ọhun. Ẹjẹ nikan lawọn dokita to n ṣetọju rẹ ko fun un.

Latigba tawọn eeyan naa si ti lu u daadaa ni ko ti sẹnikankan to sọrọ nipa iṣẹlẹ naa. Eyi gan-an lo bi Portable ninu to fi kigbe sita lati ori bẹẹdi to wa pe ṣe o digba toun ba ku kawọn eeyan too gbija oun.

 

Leave a Reply