Ọlọpaa ti mu Ọlamide, ọpọlọpọ igbo lawọn ọlọpaa ba lọwọ ẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka tipinlẹ Kwara, ti mu ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Ọlamide Oluwaṣeun, fẹsun pe o n gbe ọpọlọpọ igbo kiri l’Opopona Ganmọ/Sapatí, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, leyii ti wọn lo lodi sofin ilẹ wa.

ALAROYE gbọ pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni yii, ni ọwọ tẹ ọkunrin naa pẹlu ọpọlọpọ igbo l’Opopona Ganmọ-Sapatí, nijọba ibilẹ Ìfẹ́lódùn, ti ko si ri alaye kankan ṣe fun awọn ọlọpaa nipa bi igbo naa ṣe jẹ, to si ti n ṣẹju pẹu ni galagala ọlọpaa bayii.

ASP, Abdulmalik, to lewaju awọn ikọ ọlọpaa ẹka to n gbogun ti idigunjale ni wọn mu afurasi yii. Lasiko ti wọn n yẹ ero atawọn ọkọ wo lopopona ni ọwọ tẹ ẹ lori ọkada to wa. Idi igbo marun-un ni wọn ba lara rẹ, loju-ẹsẹ ni wọn si ti taari ẹ lọ si ẹka to n ṣe iwadii ẹsun ọdaran. Nibẹ ni wọn ti fidi iwadii wọn mulẹ pe ogbologboo ni afurasi naa ninu gbigbe igbo kiri lagbegbe Ganmọ si Sapatí.

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti taari ẹ lọ si ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, ẹsun ti wọn si fi kan an ni gbigbe igbo kiri lọna aitọ, eyi ti wọn lo ta ko awọn abala kan ninu iwe ofin ilẹ wa.

Leave a Reply