Wọn pariwo ole le kọmiṣanna ti Ayedatiwa yọ nipo lori l’Akurẹ, eyi lohun to ṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ariwo, ‘ole, ole’ lo gba ẹnu pupọ ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri ṣeto idajọ nipinlẹ Ondo, kan ni kete ti wọn gbọ pe Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, ti yẹ aga mọ gbogbo awọn kọmiṣanna nidii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii.

Ko si si ẹlomi-in tawọn oṣiṣẹ ọhun n pariwo le lori ju kọmiṣanna ti wọn yan fun eto idajọ, iyẹn Amofin Charles Titiloye, ẹni to ti n dari iṣakoso ibẹ lati bii ọdun mẹta sẹyin ti gomina ana, Oloogbe Rotimi Akeredolu, ti yan an sipo.

Boya ti kọmiṣanna ta a n sọrọ rẹ yii ba mọ pe iru ikede ojiji yii yoo waye lọjọ naa, o ṣee ṣe ko ma wulẹ yọ ara rẹ lẹnu lati yọju si ọfiisi pẹlu abuku nla tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun fi kan an.

Afi bii ẹni pe awọn oṣiṣẹ naa ti mọ tẹlẹ pe iru ikede bẹẹ yoo waye ni, nitori loju-ẹsẹ ti wọn gbọ iroyin ọhun ni gbogbo wọn ti ko ara wọn jọ bii ẹni pe wọn ti sọ fun ara wọn tẹlẹ, ti wọn si n pariwo, ‘ole, ole’ kikankikan lẹnu ọna ọfiisi kọmiṣanna, wọn ni ko ṣilẹkun, tabi ko bọ sita to ba da ara rẹ loju.

Ọpọ ninu wọn ni wọn fẹsun kan Titiloye pe ṣe lo maa n ṣe bii Ọlọrun latigba ti wọn ti yan an sipo, wọn ni ọrọ to si maa n ti ẹnu rẹ jade lọpọ igba ni pe ko sẹni to le yọ oun nipo.

Awọn ọlọpaa ni wọn pada waa gba ọkunrin ọmọ bibi ilu Akurẹ, ọhun silẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ lọjọ naa, awọn ni wọn waa gbe e kuro lọfiisi rẹ to fi raaye bọ mọ awọn tinu n bi naa lọwọ.

 

Leave a Reply