Adajọ ni Baba Ijẹṣa jẹbi koko ẹsun marun-un, lo ba bu sekun gbaragada ni kootu

Faith Adebọla

Niṣe ni ọkan gbogbo awọn to wa ni kootu ti wọn ti n gbọ ẹjọ ifipa ba ni lo pọ ti wọn fi kan ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa nni, Lanre Omiyinka, ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹṣa ko soke, nitori ko ti i sẹni to mọ ibi ti ẹjọ naa yoo fori sọ. Niṣe ni Baba Ijẹṣa bu ṣekun gbaraga bii ọmọde ni kootu nigba ti adajọ n ka awọn ẹsun rẹ ati ẹwọn ọdun mẹtala ti awọn ohun to ṣe naa pe fun.

Ninu awọn ẹri to wa niwaji Adajọ Olwatoyin Taiwo to gbọ ẹjọ naa nile-ẹjọ giga to wa ni Ikẹja lo ti sọ pe Baba Ijẹṣa jẹbi koko bii marun-un ninu awọn ẹsun mẹfa ti wọn fi kan an. Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ninu wọn jẹ ọrọ agbọsọ lasan.

Ninu awọn to ni wọn jẹ ọrọ agbọsọ ni eyi ti wọn ti sọ pe o ki kọkọrọ bọ ọmọbinrin naa nidii, ati pe o ti kọkọ fipa ba a lo pọ lọdun 2014.

Ninu awọn eyi ti Adajọ Taiwo ni o jẹbi rẹ ni pe ko si ẹri pe wọn fiya jẹ ẹ ko too di pe o sọ ọrọ to kọ silẹ fawọn ọlọpaa lagọọ wọn.

Yatọ si eyi, adajọ ni dipo bo ṣe sọ pe oun ro pe awọn n ya fiimu ni, o ni niṣe lo n bẹbẹ nigba ti wọn mu un pe ki wọn dariji oun. O ni eyi to pada waa sọ pe awọn n ya fiimu ni yẹn ki i ṣe ironu to fidi mulẹ.

Bakan naa lo sọ pe nibi to ti sọ pe awọn n ya fiimu, ko si kamẹra, ko si iwe ere ti wọn n lo, bẹẹ ni ko si awọn oṣere tiata mi-in nibẹ. Adajọ ni irọ ni o pa, ki i ṣe ootọ, nitori o ti jẹwọ nile-ẹjọ pe oun ko mọ pe kamẹra kan wa ni bonkelẹ. O ni bawo lo ṣe le maa ya fiimu nigba to sọ pe oun ko mọ pe kamẹra kan wa nibẹ.

Siwaju si i, adajọ ni ẹri wa pe o fẹẹ mu ara ọmọ naa le lo fi n la ika ọmọ naa to fi sẹnu to n pọ ọn la.

Igbẹjọ ṣi n tesiwaju.

Leave a Reply