Ile-ẹjọ ju Baba Ijẹṣa sẹwọn ọdun mẹrindinlogun

Faith Adebọla

Ẹwọn ọdun ọdun marun-un ni Adajọ Taiwo, ti ile-ẹjọ giga to jokoo ni ilu Ikẹja, nipinlẹ Eko ju oṣere tiata nni, Lanre Omiyinka ti gbogbo eeyan mọ si Baba Ijẹsa, si  lori ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.

Adajọ ni ọkunrin naa jẹbi koko ẹsun mẹrin, eyi ti ijiya akọkọ jẹ ẹwọn ọdun marun-un, ekeji jẹ ẹwọn ọdun mẹta, ẹkẹta naa jẹ ẹwọn ọdun mẹta nigba ti ẹkẹrin jẹ ẹwọn ọdun marun-un. Ṣugbọn niṣe ni yoo ṣe gbogbo ẹwọn naa papọ, eyi to fi ku si ọdun marun-un ti yoo lo lọgba ẹwọn.

Ariwo, ‘Mi o ṣe e, mi o ṣe e, loṣere naa mu bọnu nigba ti adajọ gbe idajọ rẹ kalẹ.

Leave a Reply