Idibo 2023: Ẹgbẹ APC sun ikede Shettima gẹgẹ bii ondupo igbakeji aarẹ wọn siwaju

Jọkẹ Amọri

Ti ko ba si ayipada to waye ni, Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ẹgbẹ oṣelu APC iba kede gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima, gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije dupo igbakeji aarẹ wọn ninu eto idibo ọdun to n bọ.

Ṣugbọn lojiji ni wọn sun eto naa siwaju gẹgẹ bi ọkan ninu awọn oloye ẹgbẹ naa ṣe ṣalaye fun awọn oniroyin.

ALAROYE gbọ pe igbakeji akọwe agba ẹgbẹ APC lo paṣẹ pe ki eto ṣiṣi oju Shettima han fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ yii ma waye mọ, ti ko si sọ idi pataki kankan ti ipinnu yii fi waye.

O ṣalaye pe awọn yoo kede ọjọ mi-in, ọjọọre ti eto yii yoo waye, eyi to ṣee ṣe ko jẹ oṣe to n bọ yii.

Leave a Reply