Adajọ ni ki wọn da Kanu pada si orileede Kenya ti wọn ti gbe e wale

Jọkẹ Amọri

Milịiọnu lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (500m), ni ile-ẹjọ giga kan to fikalẹ si ilu Umuahia, nipinlẹ Delta, paṣẹ pe ki ijọba apapọ san fun ajafẹtọọ ominira Biafra nni, Nnamdi Kanu, fun bi wọn ṣe tẹ ẹtọ rẹ loju labẹ ofin, bẹẹ ni wọn ni ki wọn da a pada si orileede Kenya ti won ti gbe e ni papamọra wa si Naijiria.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni idajọ naa waye labẹ idari Onidaajọ E. N. Anyadike to gbọ ẹjọ ọhun. O fidi rẹ mulẹ pe ohun ti ko bojumu ni labẹ ofin bi wọn ṣe wọ Kanu wa si Naijiria lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, lai tẹle ofin ati ilana to tọ, eleyii si tẹ ẹtọ ti ọkunrin naa ni loju mọlẹ.

Adajọ ni ijọba ko ni ẹri lati fi ta ko ẹsun ti Kanu fi kan wọn pe wọn mu oun, bẹẹ ni wọn fi nnkan di oun loju, wọn tun fiya nla jẹ oun, ti wọn si so sẹkẹsẹkẹ mọ oun lọwọ ati ẹsẹ fun ọjọ mẹjọ, ki wọn too ko oun ni papamọra pada si Naijiria.

Kanu gbe ijọba apapọ lọ sile-ẹjọ nipasẹ agbẹjọro rẹ, Aloy Ejimakor, lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, lori bi wọn ṣe gbe e wa si orileede Naijiria lati Kenya lọna aitọ.

Agbẹjọro Kanu ni oun fẹ ki ile-ẹjọ ba oun fi oju lameetọ wo bi ijọba apapọ ṣe gba ọna ti ko bofin mu taari ajafẹtọọ naa wa si Naijiria gẹgẹ bii eyi to lodi, to si ta ko ẹtọ ti ọkunrin yii ni labẹ ofin.

Bẹẹ lo ni ki ile-ẹjọ ri si bi wọn ṣe ko o ni papamọra, ti wọn fi nnkan di i loju, ti wọn de sẹkẹṣẹkẹ mọ ọn lọwọ ati lẹsẹ, ti wọn ko si jẹ ko ni anfaani lati sọ tẹnu rẹ labẹ ofin ki wọn too gbe e kuro ni Kenya  wa si Naijiria, eyi to tọna fun wọn lati ṣe.

O ni ki adajọ paṣẹ pe ọkunrin naa ko ni ẹjọ kankan lati jẹ, bẹẹ ni ki o pada sipo to wa ko too di pe wọn mu un lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021.

Gbogbo awọn ibeere yii ni adajọ yii gba wọlẹ, to si paṣẹ pe ki awọn ti wọn n ba Kanu rojọ san ẹgbẹrun lọna aadọta miliọnu (500m) fun un, ki wọn si da a pada si orileede Kenya ti wọn ti gbe e wa sile lọna aitọ, nitori ibi ti a ba ti gun igi la ti i sọ.

Leave a Reply